Microsoft Office Proofing Tools 2016 - Èdè Gẹ̀ẹ́sì
Microsoft Office Proofing Tools ń gba ìṣàtúnṣe láàyè nínú àwọn àfikún èdè.
Pàtàkì! Yíyan èdè kan nísàlẹ̀ yìí yóò ṣàyípadà gbogbo àkóónú ojú-ìwé náà sí èdè yẹn.
Ẹ̀yà:
2016
Ọjọ́ Àtẹ̀jáde:
25/5/2016
Orúkọ Fáìlì:
proofingtools2016_yo-ng-x64.exe
proofingtools2016_yo-ng-x86.exe
Ìwọ̀n títóbi Fáìlì:
1.2 MB
1.1 MB
Ṣé o fẹ́ ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ kíkọ fún èdè kan tí Office kò ṣàgbékalẹ̀ ní aládàáṣe bí? O wà ní ibi tó dára. Microsoft Office Proofing Tools ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkópọ̀ àwọn irinṣẹ́ ìjẹ́rìí tó wà nílẹ̀ fún Office nínú èdè yìí. Ṣáà ṣàgbékalẹ̀ kí o sì ṣàtúnbẹ̀rẹ̀ Office, àti irinṣẹ́ ìjẹ́rìí fún èdè rẹ ó sì ti ṣetán láti bẹ̀rẹ̀.Àwọn Ìlànà-iṣẹ́ Ẹ̀rọ tó ní Àtìlẹ́yìn
Windows 7, Windows 8, Windows Server 2008 R2
Gbígba ẹ̀dà fáìlì yìí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àtòjọ-ètò wọ̀nyí:- Microsoft Office Excel 2016
- Microsoft Office OneNote 2016
- Microsoft Office Outlook 2016
- Microsoft Office PowerPoint 2016
- Microsoft Office Word 2016
- Láti ṣàgbékalẹ̀ gbígbà ẹ̀dà fáìlì yìí:
Ṣàgbékalẹ̀ àwọn irinṣẹ́ ìjẹ́rìí:
- Gba ẹ̀dà fáìlì náà sílẹ̀ nípa ìṣíra tẹ Bọ́tìnì gbígba ẹ̀dà fáìlì (lókè) kí o sì ṣàfipamọ́ fáìlì náà sí àwo gbagidi rẹ.
- Mú àtòjọ-ètò àgbékalẹ̀ ṣiṣẹ́.
- Lórí ojú ìwé Ka Àdéhùn Àṣẹ Ẹ̀yà Àìrídìmú ti Microsoft, ṣàtúnyẹ̀wò ìfẹnukò, yan àpótí àyẹ̀wò "Ṣíra tẹ ibí láti faramọ́ Àdéhùn Àṣẹ Ẹ̀yà Àìrídìmú ti Microsoft" náà, kí o sì ṣíra tẹ Tẹ̀síwájú.
- Àmọ̀ràn àgbékalẹ̀ ń ṣiṣẹ́ ó sì ń ṣàgbékalẹ̀ àwọn irinṣẹ́ ìjẹ́rìí.
- Lẹ́yìn tí àgbékalẹ̀ náà ti parí, ṣàtúnbẹ̀rẹ̀ àwọn ìfilọ́lẹ̀ Office rẹ tó ṣí.
Àwọn ìtọ́ni fún ìlò:Ṣáà lo àwọn irinṣẹ́ ìjẹ́rìí bí o ti máa ń ṣe - báyìí o gbọ́dọ̀ rí wọn fún èdè tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàgbékalẹ̀. Fún àpẹrẹ, o le ṣètò èdè ìjẹ́rìí rẹ sí èdè titun náà láti lo àyẹ̀wò sípẹ́lì (tó bá wà nílẹ̀) - láti kọ́ bí o ti le ṣe ìyẹn, woYípo láàrín oríṣìí èdè nípa lílo Pẹpẹ èdè náà
Láti ṣàyọkúrò gbígbà ẹ̀dà fáìlì yìí:- Lórí Mẹ́nù ìbẹ̀rẹ̀, tọ́ka sí Àwọn ààtò kí o si ṣíra tẹ Pánẹ́ẹ̀lì Ìdarí.
- Ṣíra tẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì Ṣàfikún/Ṣàyọkúrò Àwọn Àtòjọ Ètò.
- Nínú àtòkọ àwọn ètò tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàgbékalẹ̀, yan Microsoft Office Proofing Tools 2016 - Èdè Gẹ̀ẹ́sì lẹ́yìn náà ṣíra tẹ Ṣàyọkúrò, Ṣèmúkúrò, tàbí Ṣàfikún/Ṣèmúkúrò. Tí àpótí ìjíròrò kan farahàn, tẹ̀lé àwọn ìtọ́ni láti ṣèmúkúrò àwọn àtòjọ ètò.
- Ṣíra tẹ Bẹ́ẹ̀ni tàbí Ó Dára láti ṣàrídájú pé o fẹ́ ṣàyọkúrò àtòjọ-ètò náà.