Ọjọ́ àtẹ̀jáde: Ọjọ́ 30, Oṣù Agẹmọ, Ọdún 2024
Ọjọ́ ìmúṣẹ: Ọjọ́ 30, Oṣù Ọwẹ́wẹ̀, Ọdún 2024
Àwọn ìfẹnukò wọ̀nyí ("Àwọn ìfẹnukò") bo ìlò àwọn àgbéjáde aṣàmúlò Microsoft, ojúlé wẹ́ẹ̀bù, àti àwọn ìpèsè tí a ṣàkójọ ní ìparí àwọn ìfẹnukò wọ́nyí níbí (https://www.microsoft.com/servicesagreement#serviceslist) "Àwọn ìpèsèná."). O gba àwọn Ìpèsè wọ̀nyí nípa ṣíṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ Microsoft kan, nípa ìlò rẹ ti Àwọn ìpèsè náà, tàbí nípa ìtẹ̀síwájú lati máa lo Àwọn Ìpèsè náà lẹ́yìn tí a ti sọ àyípadà sí Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí fún ọ.
1. Ìpamọ́ Rẹ. Ìpamọ́ rẹ ṣe pàtàkì sí wa. Jọ̀wọ́ ka Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ Microsoft (https://go.microsoft.com/fwlink/?LinkId=521839) (the "Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀") Ìkọ̀kọ̀") bí ó ti ṣe àlàyé irú àwọn détà tí à ngbà láti ọ̀dọ̀ rẹ àti láti inú àwọn ohun èlò rẹ ("Détà"), bí a ṣe nlo Détà rẹ, àti àtìlẹ́yìn òfin tí a ní láti wọlé sí Détà rẹ. Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ tún ṣàlàyé bí Microsoft ti ń lo àkóónú rẹ, èyí tííṣe ìbánisọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn; àwọn ìfiṣọwọ́ tí o firánṣẹ́ sí Microsoft nípasẹ̀ Àwọn Ìpèsè náà; àti àwọn fáìlì, fọ́tò, àkọsílẹ̀, ohun àfetígbọ́, iṣẹ́ onídíjítà, ìgbàsílẹ̀ àti fídíò tí o fiṣọwọ́, tí o fipamọ́, tí o fisórí afẹ́fẹ́, tàbí ṣẹ̀da, ṣàwari, tàbí ṣàpínlò nípasẹ̀ Àwọn Ìpèsè, ("Àkóónú Rẹ"). Níbití ìṣètò bá dá lórí ìgbaniláàyè, àti títí dé ibi tí òfin gbà wá làáyé dé, nípa fífaramọ́ Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, o gbà sí àkójọ̀ Microsoft, ìlò àti àfihàn Àkóónú Rẹ àti Détà bí a ti ṣàlàyé nínú Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ náà. Ní ọ̀nà míràn, a ó pèsè àkíyèsí míràn a ó sì bèrè fún ìyọ̀nda rẹ bí a ti tọ́kasí nínú Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ náà.
2. Àkóónú Rẹ. Púpọ̀ nínú àwọn Ìpèsè wa gbà ọ́ láàyè láti ṣẹ̀dá, fipamọ́ re, tàbí ṣàjọpín rẹ̀, láti gba ohun àmúlò láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Àwa kìí sọ pé àwa ni a ni Àkóónú Rẹ. Àkóónú Rẹ yóò má a jẹ́ tìrẹ, Ọwọ́ rẹ ló wà.
3. Òfin Ìṣesí. Àkóónú àti isesí wà lọ́wọ́ rẹ nígbàtí o bá ń lo Àwọn ìpèsè náà.
4. Lílo Àwọn Iṣẹ́ & Àtìlẹ́yìn.
5. Lílo Àwọn Ìpèsè àti Ìfilọ́lẹ̀ Ẹnìkẹta. Àwọn Ìpèsè náà le gbà ọ́ láàyè láti ráyèsí tàbí gba àwọn àgbéjáde, àwọn iṣẹ́, àwọn ojú-òpó wẹ́ẹ̀bù, àwọn ojú òpó ìsopọ̀, àkóónú, ohun ìní, àwọn ayò, ọgbọ́n-inú, àkójọpọ̀, bọ́ọ̀tì tàbí àwọn ìfilọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹta (àwọn ilé-iṣẹ́ tàbí àwọn ènìyàn tí kì í ṣe Microsoft) ("Àwọn Ìpèsè àti Ìlò-ẹ̀rọ Ẹnikẹta"). Púpọ̀ nínú àwọn Iṣẹ́ wa bákan náà máa ń jẹ́ kí o lè ṣàwárí, béèrè fún, tàbí ní àṣepọ̀ pẹ̀lú Àwọn Ìlò-ẹ̀rọ àti Àwọn Iṣẹ́, ó sì lè gbà ọ́ láàyè tàbí nílò kí o pín àwọn Àkóónú àti Dátà Rẹ pẹ̀lú irú Àwọn Ìlò-ẹ̀rọ àti Á̀wọn Iṣẹ́ Ẹnìkẹta bẹ́ẹ̀, o sì ní òye pé nípa lílo Àwọn Iṣẹ́ wa, ò ń darí wọn láti mu Àwọn Ìlò-ẹ̀rọ àti Á̀wọn Iṣẹ́ Ẹnìkẹta wà nílẹ̀ fún ọ. Àwọn Ìlò-ẹ̀rọ àti Àwọn Iṣẹ́ Ẹnìkẹta náà lè gbà ọ́ láàyè láti Fi Àkóónú tàbí Dátà rẹ pamọ́ pẹ̀lú olùgbéjáde, olùpèsè tàbí aṣètò Àwọn Ìlò-ẹ̀rọ àti Àwọn Iṣẹ́ Ẹnìkẹta náà. Àwọn Ìfilọ́lẹ̀ àti Àwọn Iṣẹ́ Ẹlòmíràn náà le fún ọ ni òfin ìpamọ́ tàbí nílò kí o gba àwọn ìfẹnukò wọn kí o tó le ṣe ìfilọ́lẹ̀ tàbí lo Àwọn Ìfilọ́lẹ̀ àti Àwọn Iṣẹ́ Ẹnìkẹta náà. Wo abala 13.b fún àwọn àfikún ìfẹnukò fún àwọn Ìlò-ẹ̀rọ tí a gbà láti inú àwọn Ibùdó Ojú-ọjà kan èyí tí Microsoft tàbí àwọn alásopọ̀ rẹ̀ ni tàbí tí wọn ń ṣàkóso (ó wà lára rẹ̀, ṣùgbọ́n kò mọ ní Ibùdó Ojú-ọjà Office, Ibùdó Ojú-ọjà Microsoft lórí Xbox àti Ibùdó Ojú-ọjà Microsoft lórí Windows nìkan. O gbọ́dọ̀ ṣàtúngbéyẹ̀wò àwọn òfin ìpamọ́ àti àwíyé ẹnìkẹta náà kí o tó gbà, ṣàmúlò, bèrè, tàbí so Àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ pọ̀ mọ́ Ìfilọ́lẹ̀ àti Iṣẹ́ Ẹnìkẹta. Èyíkéyìí àwíyé ẹnìkẹta kò ṣàtúnṣe Àwọn àwíyé wọ̀nyìí. Microsoft kò fún ọ ní ìwé-ẹ̀rí fún ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ kankan gẹ́gẹ́ bí ara Àwọn Ìlò-ẹ̀rọ àti Àwọn Iṣẹ́ Ẹnìkẹta yòówù. O gbà láti gbé gbogbo ewu àti ojúṣe tó lè wáyé nípasẹ̀ ìṣàmúlò Àwọn Ìlò-ẹ̀rọ àti Àwọn Iṣẹ́ àwọn Ẹnìkẹta rẹ wọ̀nyìí, àti pé Microsoft kò ní dúró fún àwọn ìṣòro yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ ìṣàmúlò rẹ fún wọn. Microsoft kò ní dúró tàbí dáhùn fún ọ tàbí àwọn mìíràn fún àlàyé tàbí àwọn iṣẹ́ tí Àwọn Ìfilọ́lẹ̀ àtí Àwọn Iṣẹ́ Ẹnikẹta bá pèsè.
6. Wíwà Iṣẹ́.
7. Àfikún sí Àwọn Ìpèsè tàbí Ẹ̀yà Àìrídìmú, àti Àwọn Àyípadà sí Àwọn Àdéhùn Wọ̀nyí.
8. Ìwé-Àṣẹ Ẹ̀yà Àìrídìmú. Àfi bí ó bá wá pẹ̀lú àdéhùn ìwé-àṣẹ Microsoft ọ̀tọ̀ (fún àpẹẹrẹ, bí o bá nlo ohun èlò Microsoft tó jẹ́ ara Windows, nígbà náà, àwọn Àdéhùn Ìwé-àṣẹ Ẹ̀yà àìrídìmú Microsoft fún Ètò Ìpìlẹ Kọmputa Windows ni ó ndarí irú ẹ̀yà àìrídìmú bẹ́ẹ̀), ẹ̀yà àìrídìmú yòówù tí àwa bá pèsè fún ọ gẹ́gẹ́ bí ara àwọn Iṣẹ́ náà wà lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí. Àwọn àtòjọ ètò tí a gbà nípasẹ̀ Ìbi ìpamọ́ kan tí Microsoft ni tàbí ṣàkóso tàbí àwọn tó sopapọ̀ mọ (pẹ̀lú, ṣùgbọ́n kò pin sí Office Store, Microsoft Store lórí Windows àti Microsoft Store lórí Xbox) wà ní abala 13.b.i nísàlẹ̀.
9. Àwọn Àdéhùn Ìsanwó. Bí o bá ra Iṣẹ́ kan, nígbà náà, àwọn àdéhùn owó sísan wọ̀nyí kan ọjà rírà rẹ, ìwọ sì faramọ́ wọn.
10. Ẹnití nbá ni dá Májẹmù, Àṣàyàn Òfin, & Ibití a ó ti Parí Àríyàjiyàn. Fún ìlò rẹ ti Àwọn Iṣẹ́ olórúkọ Skype ti ọ̀fẹ́ àti oníbàárà tí ń sanwó, tí o bá ń gbé lóde Europe, Middle East àti Africa, o ń ṣàdéhùn pẹ̀lú, gbogbo ìtọ́kasí "Microsoft" nínú Àwọn Àwíyé wọ̀nyí túmọ̀ sí, Skype Communications S.à.r.l, 23 – 29 Rives de Clausen, L-2165 Luxembourg. Fún Àwọn Iṣẹ́ olórúkọ Skype ti ọ̀fẹ́ tàbí oníbàárà tí ń sanwó, tí o bá ń gbé lóde Europe, Middle East àti Africa, òfin Luxembourg ń darí ìtúmọ̀ ti Àwọn Àwíyé àti ìbèrè fún dídalẹ̀ kọ̀ọ̀kan, láì fi ti àwọn ìlànà òfin aáwọ̀ ṣe. Òfin ìpínlẹ̀ tàbí orílẹ̀-èdè ibiti iwọ ngbé ni o ndarí gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ (eyiti o kan gbígba ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin ìpínlẹ̀ fún ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, òfin fífiga-gbága ti kò tọ́, ati nínú òfin ti ndarí ìwà àìtọ́. Tí o bá ń gbé lóde Europe, Middle East àti Africa, ìwọ àti àwa gbà sí agbègbè àti ibi àwọn ilé-ẹjọ́ ti Luxembourg fún gbogbo aáwọ̀ tó le jáde láti tàbí tó jọmọ́ onibàárà ti Àwọn ìpèsè olórúkọ ti Skype. Fún gbogbo Iṣẹ́ míràn, àjọ tí o ń ti ipasẹ̀ wọn ṣàdéhùn, òfin tí ń darí, àti ibi láti yanjú àwọn aáwọ̀ farahàn nísàlẹ̀:
Oníbàárà ìkẹyìn agbègbè rẹ lè nílò àwọn òfin agbègbè láti darí tàbí láti fún ọ ní ẹ̀tọ́ láti yanjú àríyànjiyàn ní ibòmíràn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Àdéhùn wọ̀nyí wà. Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àṣàyàn òfin àti ìpèsè ibòmíràn ní apá 10 yóò ní ipa dé ibití àwọn òfin agbègbè rẹ bá gba ni láàyè dé.
11. Àwọn àtìlẹ́yìn ọjà.
O tún ní ẹ̀tọ́ láti yàn tàbí ìrọ́pò fún àwọn ìkùnnà gbógì pẹ̀lú àwọn ọjà. Tí ìkùnnà kan sí ọjà tàbí iṣẹ́ kò bá tó ìkùnnà gbógì, o ní ẹ̀tọ́ sí àtúnṣe ìkùnnà náà láàrín àkókò díẹ̀. Tí a kò bá ṣe èyí o ní ẹ̀tọ́ sí owó àsanpadà fún ọjà náà kí o sì fagilé àdéhùn náà fún iṣẹ́ náà kí o sì gba owó àsanpadà fún abala tí o kò lò. O tún ní ẹ̀tọ́ fún owó gbà má bínú fún èyíkéyìí ìdíbàjẹ́ tàbí àdánù tí a le rí nítorí ìkùnnà kan nínú ọjà tàbí iṣẹ́.
12. Ìdíwọ̀n Ojúṣe.
13. Àwọn Àdéhùn tó kan àwọn Iṣẹ́ kan pàtó. Àwọn àdéhùn tó wà ṣáájú àti lẹ́yìn apá 13 kan gbogbo àwọn Iṣẹ́ lápapọ̀. Apá yìí ní àwọn àdéhùn tó kan àwọn iṣẹ́ kan pàtó nínú, àwọn èyí tó jẹ́ àfikún sí àwọn àdéhùn gbogbogbò. Àwọn àdéhùn tó níí ṣe pẹlú ìpèsè kan pàtó wọ̀nyí ni a ó lò bí aáwọ̀ yòówù bá jẹyọ pẹ̀lú àwọn àdéhùn gbogbogbò.
14. Oníruru. Abala yìí, àti abala 1, 9 (fún iye owó tó yẹ fún sísan ṣáájú òpin àwọn Àdéhùn wọ̀nyí), 10, 11, 12, 15, 17 àti àwọn tó jẹ́ pé nípasẹ̀ àdéhùn wọn, wọn yóò ní ipa lẹ́yìn tí àwọn Àdéhùn wọ̀nyí bá ti parí, yóò rékọjá ìfòpinsí tàbí fífagilé yòówù fún àwọn Àdéhùn wọ̀nyí. Títí dé ibití òfin tó yẹ gba ni láàyè dé, a lè pín àwọn Àdéhùn wọ̀nyí fún ni, gbé ojúṣe wa fún ẹlòmíràn lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, tàbí kí a fún àwọn ẹlòmíràn ní ìwé-àṣẹ fún àwọn ẹ̀tọ́ wa lábẹ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, nígbà yòówù láì sọ fún ọ. O kò gbọdọ̀ pín àwọn Àdéhùn wọ̀nyí fún ni tàbí kí o fi ẹ̀tọ́ yòówù láti lo àwọn Iṣẹ́ náà fún ẹlòmíràn. Èyí ni gbogbo àdéhùn láàárín ìwọ àti Microsoft fún ìmúlò rẹ fún àwọn Iṣẹ́ náà. O rékọjà àdéhùn ìṣáájú yòówù láàárín ìwọ àti Microsoft nípa ìmúlò rẹ fún àwọn Iṣẹ́ náà. Ní fífaramọ́ àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, ìwọ kò gbáralé gbólóhùn yòówù, ìṣojú fún ni, àtìlẹ́yìn, òye, ìlérí tàbí ìfinilọ́kànbalẹ ju bí a ti sọ nínú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí lọ. Gbogbo abala àwọn Àdéhùn wọ̀nyí yóò ní ipa títí dé ibití òfin tó yẹ gba ni láàyè dé. Bí ilé-ẹjọ́ kan tàbí onílàjà bá ṣe ìdájọ́ pé a kò lè lo abala kan lára àwọn Àdehùn wọ̀nyí bí a ti kọ ọ́, a lè fi àwọn àdéhùn tó jọ́ èyí rọ́pò àwọn irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ títí dé ibití wọ́n ti ṣeé lò dé lábẹ́ òfin tó yẹ, ṣùgbọ́n àwọn tó kù lára àwọn Àdéhùn wọ̀nyí kì yóò yípadà. Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí wà fún ànfàní ìwọ àtí àwa nìkan. Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí kò sí fún ànfàní ẹlòmíràn, àfi fún àwọn tí yóò jogún Microsoft àti àwọn tí Microsoft bá yàn. Àkórí-ọ̀rọ̀ àwọn abala wà fún ìtọ́kasí nìkan, wọn kò sì ní ipa kankan lábẹ́ òfin.
15. A Gbọ́dọ̀ Mú Ẹ̀sún Wá Láàárín Ọdún Kan. Ẹ̀sùn yòówù tó bá níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tàbí àwọn Iṣẹ náà ni a gbọ́dọ̀ mú wá sí ilé-ẹjọ́ (tàbí sọ́dọ̀ onílàjà bí abala 10.d bá ní ipa) láàárín ọdún kan sí ọjọ́ tí ó lè kọ́kọ́ mú ẹ̀sùn náà wá, àfi bí òfin agbègbè rẹ bá nílò àkókò tó ju èyí lọ láti mú ẹ̀sùn wá. Bí o kò bá múu wá láàárín àkókò náà, ó ti di ohun tí a dínà mọ́ láíláí.
16. Àwọn Òfin Ọjà Gbígbé Lọ Sí Òkèèrè. O gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún gbogbo òfin àti ìlànà gbígbé ọjà lọ si ilẹ òkèèrè fún títà ti ìlú ẹni àti ti ilẹ òkèèrè ti o kan software àti/tàbí Iṣẹ́ náà, èyí tí ó kan ìhámọ́ ní ibití a ngbé ọjà lọ, awọn aṣàmúlò ìkẹyìn, àti ìmúlò ìkẹyìn. Fún àlàyé síwájú síi nípa àwọn ìhámọ́ lórí ilẹ̀ àti ti gbígbé ọjà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fún títà, lọ sí https://www.microsoft.com/exporting.
17. Ìtọ́jú Ẹ̀tọ́ àti Ìjábọ̀. Àyàfi bí a ti pèsè lábẹ́ Àwọn Àdéhùn wọ̀nyí, Microsoft kò fún ọ ní ìwé àṣẹ tàbí èyíkéyìí ẹ̀tọ́ míràn bó ti wù kó rí lábẹ́ àṣẹ kankan, bí o ti le ṣeé, ẹ̀tọ́ ìtajà, àṣírí ìṣòwò, àmì òwò tàbí ohun ìní àkọsílẹ̀ míràn tí a ni tàbí tí Microsoft ń darí tàbí èyíkéyìí ilé-iṣẹ́ tójọra, pẹ̀lú ṣùgbọ́n kò pín sí orúkọ kankan, ìmúra òwò, àmì ìdánimọ̀ tàbí ohun míràn tójọra. Tí o bá fun Microsoft ní ọgbọ́n-inú kankan, ìwé àgbéyẹ̀wò, àbà tàbí ìjábọ̀, pẹ̀lú ọgbọ́n-inú àìlópin fún àgbéjáde titun, ìmọ̀-ẹ̀rọ́, ìpolówó ọjà, orúkọ àgbéjáde, ìjábọ̀ àgbéjáde àti ìmúgbòrò àgbéjáde (""Ìjábọ̀""), tí o fún Microsoft, láì díyelé, owó àjẹmọ́nù tàbí ojúṣe míràn fún ọ, ẹ̀tọ́ láti ṣe, tí o ti ṣe, ṣẹ̀dá àwọn iṣẹ́ àwárí, lò, ṣàpínlò kí o sì ṣòwò Ìjábọ̀ rẹ ní ọ̀nàkọnà àti fún èrèdí kankan. O kò ní fún ní Ìjábọ̀ tó wà lábẹ́ ìwé àṣẹ tó nílò kí Microsoft fún ẹ̀yà àìrídìmú, ìmọ̀-ẹ̀rọ tàbí ṣíṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ìwé-àṣẹ sí ẹnikẹta kankan nítorí Microsoft ṣàfikún Ìjábọ̀ rẹ nínú wọn.
Àwọn àkíyèsi àti ìlànà fún mímú ẹ̀sùn wá fún títàpá sí ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ ẹni. Microsoft nbọ̀wọ̀ fún àwọn ẹ̀tọ́ ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ àwọn ẹlòmíràn. Bí o bá fẹ́ fi àkíyèsi nípa ìtàpá sí ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ rẹ ránṣẹ́, èyí tí ó kan ẹ̀sùn fún ìtàpá sí ẹ̀tọ́ ọjà-títa, jọ̀wọ́ lo ìlànà tó wa fún fífi ránṣẹ́ Àwọn Àkíyèsi Ìtàpásí (https://www.microsoft.com/en-us/legal/intellectualproperty/infringement) àwọn ètò wo lo kò ara Àwọn àdéhùn yìí jọ. ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÓ ṢE PÀTÀKÌ SÍ ÌLÀNÀ YÌÍ NÌKAN NI A Ó FÈSÌ.
Microsoft a má a lo àwọn ìlànà tí a gbékalẹ̀ ni Àkórí 17, Kóòdù United States, Abala 512, àti, ibi tó yẹ, Chapter III of Regulation (EU) 2022/2065, láti fèsì sí àwọn àkíyèsi nípa ìtàpá sí ẹ̀tọ́ ọjà-títa. Ní àwọn ìgbà tó yẹ, Microsoft lè mú àkọọ́lẹ̀ àwọn aṣàmúlò àwọn iṣẹ́ Microsoft tó jẹ́ olùtàpá sí ẹ̀tọ́ nígbà gbogbo má ṣiṣẹ́ tàbí kí ó múu dópin. Fún ìlọsíwájú si, ní àwọn ipò to yẹ, Microsoft lè dá àwon ìfitónilétì ìṣètò dúrò díẹ̀ nípasẹ̀ àwọn olúkúlùkù tàbí àwọn ǹkan tó má ń fa àwọn ìfitónilétì kalẹ̀ lemọ́lemọ́. Àlàyé síwájú si ti àwọn ètò tó níṣe fún Ìpèsè, pẹ̀lú àtúnṣe fún àwọn ìpinu tí Microsoft ṣe gẹ́gẹ́ bí ara àwọn ètò wọ̀nyí, ní a le rí ní Àwọn àkíyèsí Ìtàpasófin (https://www.microsoft.com/legal/intellectualproperty/infringement).
Àwọn àkíyèsi àti ìlànà nípa ohun tó níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ nínú ìpolówó ọjà. Jọ̀wọ́ ṣàtúnyẹ̀wò Àwọn Ìtọ́sọ́nà nípa Ohun-ìní Iṣẹ́ Ọpọlọ (https://go.microsoft.com/fwlink/?LinkId=243207) nípa àwọn ohun tó níí ṣe pẹ̀lú ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ nínú nẹtiwọki ìpolówó ọjà.
Àwọn àkíyèsi nípa ẹ̀tọ́ ọjà-títà àti ààmì ọjà-títà. Àwọn Ìpèsè náà jẹ́ ẹ̀dà àṣẹ © Microsoft Corporation àti/tàbí àwọn olùpèsè rẹ, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà ní ìpamọ́. Àwọn Àwíyé náà ṣàmúlò Microsoft Trademark & Brand Guidelines (https://www.microsoft.com/en-us/legal/intellectualproperty/trademarks/usage/general.aspx) (bí a ti ń ṣàtúnṣe láti ìgbàdégbà). Microsoft àti àwọn orúkọ, àmì ìdánimọ̀, àti àwọn àwòrán ti gbogbo àgbéjáde Microsoft, ẹ̀yà àìrídìmú, àti àwọn iṣẹ́ le jẹ́ yálà àìforúkọsílẹ̀ tàbí àmì òwò tí a kọsílẹ̀ ti ilé iṣẹ́ àpapọ̀ Microsoft ní Amerika àti/tàbí àwọn agbègbè míràn. Ìwọ̀nyí ni àkójọ̀ àmì ìṣòwò Microsoft tí a kọsílẹ̀ ṣùgbọ́n tó jù bẹ́ẹ̀ lọ ní https://www.microsoft.com/en-us/legal/intellectualproperty/trademarks/EN-US.aspx. Àwọn orúkọ àwọn ilé-iṣẹ́ àti ọjà gidi lè jẹ́ ààmì ọjà-títà àwọn oníhun wọn. Àwọn ẹ̀tọ́ yòówù tí a kò fífún ni nínú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí wà ní ìpamọ́. Àwọn ẹ̀yà àìrídìmú tí a lò ní àwọn olùpín àyè ayélujára Microsoft kan dá lórí iṣẹ́ òmìnira Ẹgbẹ́ JPEG. Copyright © 1991-1996 Thomas G. Lane. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà ni ìpamọ́. ẹ̀yà àìrídìmú "gnuplot" tí a ń lò nínú àwọn apèsè ojúlé wẹ́ẹ̀bù Microsoft kan jẹ́ tí àṣẹ ìtajà © 1986‑1993 Thomas Williams, Colin Kelley. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà ni ìpamọ́.
Àkíyèsi Ìtọ́jú Ìlera. Microsoft kìí pèsè ìtọ́jú ìlera tàbí ìmọràn ìtọ́jú ìlera, ìwádìí àti àyẹwò àìsàn tàbí ìtọ́jú yòówù. Má a wá ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ dọkítà rẹ tàbí àwọn àkọṣẹmọṣẹ olùpèsè iṣẹ ìlera mìíràn nípa ìbéèrè yòówù tí o lè ní nípa ipò ìlera kan, oúnjẹ, tàbi ètò wíwà ní àlàáfíà. Máṣe fojú fo ìmọ̀ràn ìtọ́jú ìlera tàbí kí o sọ àsìkò nù ní wíwá a rí nítorí àlàyé tí o wọlé sí lórí tàbí nípasẹ àwọn Iṣẹ́ náà.
Àwọn àlàyé iye owó tó wà lórí ilé-iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan àti détà rẹ (èyí tó kan iye ìtọ́kasí). Ìwífún ìṣòwò tí o pèsè nípasẹ̀ Àwọn ìpèsè náà wà fún ìlò ti ara rẹ, èyí tí kìn ṣe ọrọ̀ ajé. O kò gbọ́dọ̀ lo èyíkèyí lára àwọn détà ìṣúná tàbí àwọn ààmì èyíkèyí àṣẹ ẹlòmíràn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú onígbọ̀wọ́, títajà, ṣíṣòwò, tàbí mímú ìlọsíwájú bá àwọn irin-iṣẹ́ ìṣúná owó tàbí àwọn ọjà ìfọwóṣòwò yóòwù (fún àpẹrẹ ọjà tí a ṣe ní àkànṣe, àwọn owó ìfiṣòwò, àwọn owó pàṣípàrọ̀ òwò, àwọn ètò ìfowóṣòwò, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, níbití iye owó, ìdápadà tàbí ìṣesí irin-iṣẹ́ tàbí ọjà ìfiṣòwò náà dá lórí, tàbí níí ṣe pẹ̀lú, tàbí gbèrò láti tọpasẹ èyíkèyí fún èyíkèyí pẹ̀lú détà ìṣúnà) láì gba ìfọwọ́sí pẹ̀lú àṣẹ ẹnikẹta.
Àkíyèsi Ìṣúná Owó. Microsoft kìí ṣe adíìnádúrà/alágbàtà tàbí olùdámọràn ìfowóṣòwò tó ní àṣẹ lábẹ òfin ààbò ìjọba àpapọ United States ní àwọn ipò ìdájọ́ mìíràn, òun kìí sì fún ni ní ìmọràn nípa fífowóṣòwò, rírà, tàbí títa àwọn ọjà tó ní ààbò tàbí àwọn ọjà tàbí iṣẹ ìṣòwò mìíràn. Kò sí ohunkóhun nínú àwọn Iṣẹ yìí tó jẹ ìfilọ tàbi ẹ̀bẹ̀ láti ra tàbí ta ọjà tó ní ààbò yòówù. Yálà Microsoft tàbí àwọn tó nfún ni ní ìwé-àṣẹ lábẹ rẹ fún àlàyé iye owó tó wà lórí ilé-iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tàbí détà ìtọkasí ní ó fọwọsi tàbí dámọràn ọjà tàbí iṣẹ ìṣúná owó kan pàtó. Kò sí ohun kankan nínú Àwọn Ìpèsè náà ti a ṣe láti jẹ́ ìmọ̀ràn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, pẹ̀lú àìní òdíwọ̀n, ìdókòwò tàbí ìmọ̀ràn owó-orí.
Àkíyèsi nípa gègé ìdíwọ̀n Fidio H.264/AVC àti VC-1. Lára ẹ̀yà àìrídìmú náà lè jẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ H.264/AVC àti/tàbí VC-1 tí MPEG LA, L.L.C fún ní ìwé-àṣe. Iṣẹ́ ìmọ ẹ̀rọ yìí jẹ ìlànà àfúnpọ détà fún àlàyé fidio. MPEG LA, L.L.C. nílò àkíyèsi yìí:
A FÚN NI NÍ ÌWWÉ-ÀṢẸ FÚN ỌJÀ YÌÍ LABẸ ÌWÉ-ÀṢẸ H.264/AVC, ÀTI VC-1 FÚN ÌMÚLÒ ARA ẸNI LÁÌFIṢÒWÒ FÚN AṢÀMÚLÒ ÌKẸYÌN LÁTI (A) FI KÓÒDÙ SÍ FIDIO NÍ ÌBÁMU PẸLU GÈGÉ ÌDÍWỌN (¨ÀWỌN GÈGÉ ÌDÍWỌN´) ÀTI/TÀBÍ (B) YỌ KÓÒDÙ KÚRÒ LÁRA FIDIO H.264/AVC, ÀFOJÚRÍ MPEG-4, ÀTI VC-1 TÍ A FI KÓÒDÙ SÍ NÍPASẸ AṢÀMÚLÒ ÌKẸYÌN TÍ NṢE OHUN ÀMÚṢE TI ARA ẸNI LÁÌFIṢÒWÒ, ÀTI/TÀBÍ TÍ A GBÀ LÁTI ỌWỌ OLÙPÈSÈ FIDIO TÓ NÍ ÌWÉ-ÀṢẸ LÁTI PÈSÈ IRÚ FIDIO BẸẸ. A KÒ FÚN NI NÍ ÌWÉ-ÀṢẸ TÀBÍ A KÓ GBÈRÒ RẸ FÚN ÌMÚLÒ MÌÍRÀN. ÀFIKÚN ÀLÀYÉ NI A LÈ GBÀ LÁTI ỌWỌ MPEG LA, L.L.C. WO MPEG LA WEBSITE (https://www.mpegla.com).
Fún èrèdí ìmúdánilójú nìkan, àkíyèsi yìí kò fi àlà sí tàbí dènà ìmúlò ẹya àìrídìmú tí a pèsè labẹ àwọn Àdéhùn wọnyi fún ìmúlò ìṣòwò tó jẹ ti ara ẹni tí kò kan (i) àtúnpín kiri ẹya àìrídìmú náà fún àwọn ẹlomiran, tàbí (ii) ṣiṣẹda ohun àmúlò pẹlu GÈGÉ IDIWỌN FIDIO tó bá iṣẹ imọ ẹrọ fún pípín kiri fún àwọn ẹlomiran mu.
Àkíyèsi nípa gègé ìdíwọ̀n Fidio H.265/HEVC. Ẹyà àìrídìmú lẹ pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀rọ H.265/HEVC. Ìlọsíwájú Ìráyèsí LLC LA, L.L.C. nílò àkíyèsi yìí:
TÍ Ó BÁ PẸLÚ, ÌMÒ ẸRỌ H.265/HEVC NÍNÚ ẸYÀ ÀÌRÍDÌMÚ YÌÍ NI Ó JẸ BÍBÒ NÍPASẸ ÌKAN TÀBÍ PÚPỌ ÀWỌN ÈTÓ TI ÀTÒKỌ ÌTÓSÍ NÍ: PATENTLIST.ACCESSADVANCE.COM. TÓ DÁ LÓRÍ BÍ O ṢE GBA ÈYÀ ÀÌRÍDÌMÚ NÁÀ, ÀBÁJÁDE YÌÍ LÈ NÍ ÌWÉ ÀṢẸ LÁBÉ ÈKA ÌTÓSÍ ÌLÓSÍWÁJÚ HEVC.
Tí ẹ̀yà àìrídìmú yìí bá ṣàfilọ́lẹ̀ lórí ohun èlò Microsoft, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé àfikún ìwé àṣẹ ní a lè rí ní: aka.ms/HEVCVirtualPatentMarking.
ÀWỌN ÀDÉHÙN ÌWÉ-ÀṢẸ OHUN ÈLÒ DÉÉDÉ
MICROSOFT STORE, MICROSOFT STORE LÓRÍ WINDOWS, ÀTI MICROSOFT STORE LÓRÍ XBOX
Àwọn àdéhùn ìwé-àṣẹ wọ̀nyí jẹ́ ìfohùnṣọ̀kàn láàárín ìwọ àti olùgbéjáde ohun èlò náà. Jọ̀wọ́ kà wọ́n. Èyí kan àwọn ìṣàfilọ́lẹ̀ ẹ̀yà àìrídìmú tí o gbà sílẹ̀ láti Ìtajà Oníforíkorí Microsoft, Microsoft Store on Windows tàbí Microsoft Store on Xbox (ìkọ̀ọ̀kan èyí tí a ń pè ní "Ìtajà Oníforíkorí" nínú àdéhùn ìgbaniláyè wọ̀nyí), pẹ̀lú èyíkéyìí àfikún tàbí àfikún ìmúdára fún ìṣàfilọ́lẹ̀ náà, àyàfi tí ìṣàfilọ́lẹ̀ náà bá wá pẹ̀lú àdéhùn ọ̀tọ̀tọ̀, nínú èyítí a ń ṣàmúlò àdéhùn wọ̀nyí.
NÍPA GBÍGBÉWÁLẸ̀ TÀBÍ LÍLO OHUN ÈLÒ NÁÀ, TÀBÍ GBÍGBÌYÀNJÚ LÁTI ṢE ÈYÍKÉÈYÍ NÍNÚ ÀWỌN WỌ̀NYÍ, ÌWỌ FARAMỌ́ ÀWỌN ÀDÉHÙN WỌ̀NYÍ. BÍ O KÒ BÁ FARAMỌ́ WỌN, ÌWỌ KÒ NÍ Ẹ̀TỌ́ LÁTI, O KÒ SÌ GBỌDỌ̀ GBÉ OHUN ÈLÒ NÁÀ WÁLẸ̀ TÀBÍ KÍ O LÒÓ.
Olùtẹ̀jáde ìṣàfilọ́lẹ̀ náà túmọ̀ sí ẹni tí ń fún ọ ní ìgbaniláyè sí ìṣàfilọ́lẹ̀ náà, bí a ti dáamọ̀ nínú Ìtajà Oníforíkorí náà.
Bí o bá mú àwọn àdéhùn ìwé-àṣẹ wọ̀nyí ṣe, ìwọ ní àwọn ẹ̀tọ́ tí a kọ sí ìsàlẹ̀ wọ̀nyí.
Ìhámọ́ naa tun kan:
O tún ṣì ní ipa bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé:
Àwọn ọjà, ohun èlò àti iṣẹ wọnyi ni Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft kàn, ṣugbọn wọn lè má wà ní ọjà rẹ.