Trace Id is missing

Àdéhùn Àwọn Ìpèsè rẹ tí a mú yé ni síi

Àwa nmú Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft dójú ìwọ̀n, èyí tí ó kan bí o ti nlo àwọn àgbéjáde tàbí ìpèsè Microsoft lórí ayélujára fún aṣàmúlò ìkẹyìn. Àwa nṣe àwọn ìmúdójúìwọ̀n wọ̀nyí láti lè mú àwọn àdéhùn wa ye ni yékéyéké, àti láti ríi dájú pé wọ́n jẹ́ ohun tó hàn kedere sí ọ, àti kí wọ́n bá a lè ní ipa lórí àwọn àgbéjáde, ìpèsè àti àfidámọ̀ Microsoft titun.

Àwọn ìmúdójúìwọ̀n wọ̀nyí, tí a sọ ní ṣókí nísàlẹ yìí, yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ 30, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2023. Bí o bá tẹ̀síwájú láti máa lo àwọn àgbéjáde àti ìpèsè wa ní tàbí lẹ́yìn ọjọ́ 30, oṣù Kẹsan, ọdún 2023, ìwọ n faramọ́ Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft náà tí a mú dójú ìwọ̀n.

Àwọn Ìbéèrè Ìgbàgbogbo

Kí ni Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft?

Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft jẹ àdéhùn láàárín ìwọ àti Microsoft (tàbí ọ̀kan nínú àwọn aláàbáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀), èyí tí ó nṣàkóso lílò àwọn àgbéjáde àti ìpèsè aṣàmúlò ìkẹyìn Microsoft lórí ayélujára. O lè rí àkójọ àwọn àgbéjáde àti ìpèsè tí èyí kàn náà lẹkunrẹrẹ níbí.

Àwọn àgbéjáde àti ìpèsè wo ni Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft kò kàn?

Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft náà kò kan àwọn ọjà àti ìpèsè tí a yàsọ́tọ̀ fún àwọn oníbàárà tó ní ìwé àṣẹ fún ohun tó pọ̀, bíi Microsoft 365 fún okòwò kékèké, àwọn oníbàárà ìkẹ́kọ̀ọ́, tàbí ìjọba, Azure, Yammer, tàbí Skype for Okòwò. Fún ìfarasìn nípa ààbò, ohun ìkọkọ àti ìmúṣe pẹ̀lú àlàyé tó níí ṣe pẹ̀lú èyí, àwọn èyí ti ó kan Microsoft 365 fún okòwò, jọwọ lọ sí Ibi Àgbẹ́kẹ̀lé Microsoft ní https://www.microsoft.com/trust-center/product-overview.

Àwọn àyípadà wo ni Microsoft nṣe sí Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft?

A ti pèsè àlàyé ní ṣókí nípa àwọn àyípadà tó ṣe kókó níbí.

Láti lè rí gbogbo àwọn àyípadà náà, a gbà ọ́ níyànjú láti ka ẹ̀kunrẹ́rẹ́ Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft.

Ìgbà wo ni àwọn àdéhùn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní ipa?

Àwọn ìmúdójúìwọ̀n sí Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ 30, oṣù Kẹsan, ọdún 2023. Títí di àkókò náà, àwọn àdéhùn rẹ ní báyìí yóò ṣì má a ní ipa.

Báwo ni èmi yóò ṣe faramọ́ àwọn àdéhùn wọ̀nyí?

Nípa lílo àwọn àgbéjáde àti ìpèsè wa ní tàbí lẹ́yìn ọjọ́ 30, oṣù Kẹsan, ọdún 2023, ìwọ n faramọ́ Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft náà tí a mú dójú ìwọ̀n. Bí o kò bá faramọ́ ọ, o lè yàn láti mú ìṣàmúlò àwọn ọjà àti ìpèsè náà dópin, kí o sì mú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ dópin pẹ̀lú kí ó tó tó ọjọ́ 30, oṣù Kẹsan, ọdún 2023.