ÀWỌN ÀDÉHÙN ÌTAJÀ MICROSOFT

A múu dójú ìwọ̀n ní Oṣù Kejì, Ọdún 2017

Káàbọ sí Ibi ìpamọ́ orí ayélujára àti aláàlétà ti Microsoft. ¨Ibi ìpamọ́¨ ntọ́ka sí àwọn ipò ayélujára àti ti àlétà tó gbà ọ́ láàyè láti lọ kiri, wò nkan, jèrè nkan, rà nkan, ati láti ṣe ìdíwọ̀n dídára tàbí ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ọjà àti iṣẹ́, èyí tí ó kan àwọn ẹ̀rọ, àwọn àtẹ ìṣàkóso eré, àkóónú oní-nọ́mbà, àwọn ohun èlò, àwọn eré, àwọn ìpèsè, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí (¨Àwọn Àdéhùn Ìtajà¨) kan ìṣàmúlò Ibi ìpamọ́ Microsoft, Ibi ìpamọ́ Office, Ibi ìpamọ́ Xbox, Ibi ìpamọ́ Windows, àti àwọn iṣẹ́ Microsoft mìíràn tó tọ́ka sí Àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí (lápapọ̀ ¨Ibi ìpamọ́¨). Nípasẹ̀ Ibi ìpamọ́ náà, Microsoft a má a pèsè ànfààní àti wọlé sí oríṣiríṣi àwọn ohun amúṣẹ́dẹrùn, àwọn èyí tí ó kan àwọn ààyè àgbéwálẹ̀, ẹ̀yà àìrídìmú, àwọn irin-iṣẹ́, àti àlàyé nípa ẹ̀yà àìrídìmú, àwọn ìpèsè àti àwọn ọjà mìíràn (lápapọ̀ ¨Àwọn Ìpèsè¨ àti pẹ̀lú Ibi ìpamọ́, ¨Ibi ìpamọ́¨). Púpọ̀ lára àwọn ọjà, ìpèsè àti àkóónú náà tó wà ní Ibi ìpamọ́ náà jẹ́ àwọn ọjà àwọn ẹlòmíràn tí àwọn ẹni tó yàtọ̀ sí Microsoft gbé kalẹ̀. Nípa lílo Ibi ìpamọ́ náà, tàbí nípa ríra àwọn ọjà àti ìpèsè láti Ibi ìpamọ́ náà, ìwọ gbà, o sì faramọ́ Àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí, Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ ti Microsoft (wo abala Ohun ìkọ̀kọ̀ àti Ìdáàbòbo Àlàyé Ara-ẹni nísàlẹ̀ yìí), àti àwọn àdéhùn àti májẹ̀mú tó yẹ, àwọn ìlànà tàbí ìkọ̀sílẹ̀ tí a bá nínú Ibi ìpamọ́ náà tàbí tí a mẹ́nubà nínú àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí (lápapọ̀ ¨Àwọn Ìlànà Ibi ìpamọ́¨). A gbà ọ́ níyànjú láti ka Àwọn Ìlànà Ibi ìpamọ́ náà dáradára. O KÒ GBỌDỌ̀ LO IBI ÌPAMỌ́ TÀBÍ ÌPÈSÈ NÁÀ BÍ O KÒ BÁ FARAMỌ́ ÀWỌN ÌLÀNÀ IBI ÌPAMỌ́ NÁÀ.

Bí a bá ní Ibi ìpamọ́ Aláàlétà ti Microsoft ní orílẹ̀-èdè tàbí agbègbè rẹ, ó lè ní àwọn ìlànà tó yàtọ̀ tàbí tó jẹ́ àfikún. Microsoft lè mú àwọn ìlànà yòówù dójú ìwọ̀n, tàbí kó yí wọn padà nígbà yòówù, láì sọ fún ẹnikẹ́ni.

Àwọn Àdéhùn tó níí ṣe Pẹ̀lú Ìṣàmúlò Ibi ìpamọ́

1. Àkọọ́lẹ̀ Ọmọ-ẹgbẹ́. Bí Ibi ìpamọ́ náà bá nílò pé kí o ṣí àkọọ́lẹ̀ kan, o gbọ́dọ̀ parí ìlànà ìforúkọsílẹ̀ náà nípa fífún wa ní àlàyé tó péye titun jùlọ lẹkunrẹrẹ, tí fọ́ọ̀mù ìforúkọsílẹ tó tọ́ náà bèèrè fún. A tún lè ní kí o fọwọ́sí àdéhùn ìpèsè kan tàbí àwọn àdéhùn ìmúlò mìíràn gẹ́gẹ́ bí ara àgbékalẹ̀ fún ṣíṣí àkọọ́lẹ̀ náà. Ìṣàmúlò àkọọ́lẹ̀ náà láti wọlé sí Ibi ìpamọ́ náà àti sí àkóónú tí o rà láti Ibi ìpamọ́ náà wà lábẹ́ gbogbo àwọn àdéhùn tí ndarí àkọọ́lẹ̀ Microsoft náà. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ wo Àdéhùn Àwọn Ìpèsè Microsoft. Ojúṣe rẹ ni láti pa àlàyé àti ọ̀rọ̀ aṣínà àkọọ́lẹ̀ rẹ mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun àṣírí, ìwọ sì ni ó ni ojúṣe fún gbogbo ohun tó lè wáyé lábẹ́ àkọọ́lẹ̀ rẹ.

2. Kò Sí Ìṣàmúlò Tó Lòdì Sí Òfin tàbí Èyítí a ti fi Òfin dè. Gẹ́gẹ́ bí ara májẹ̀mú fún ìṣàmúlò Ibi ìpamọ́ àti Àwọn Ìpèsè náà, ìwọ ṣe ìlérí fún wa pé ìwọ kì yóò lo Ibi ìpamọ́ náà fún ohun yòówù tó lòdì sí òfin tàbí tí Àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí, Àwọn Ìlànà Ibi ìpamọ́ náà, tàbí àdéhùn mìíràn yòówù tó níí ṣe pẹ̀lú ìṣàmúlò Ibi ìpamọ́ náà ti fi òfin dè. Ìwọ kò gbọdọ̀ lo Ibi ìpamọ́ náà ní ọ̀nà yòówù tó lè ba apèsè Microsoft yòówù tàbí (àwọn) nẹ́tíwọọ̀kì tó ní àsopọ̀ pẹ̀lú apèsè Microsoft jẹ́, tó lè múu má ṣiṣẹ́, tó lè di ẹrù tó ti wúwo jù lée lórí, tàbí to lè mú ìfàsẹ́yìn báa, tàbí tó lè mú ìdíwọ bá ìṣàmúlò àti ìgbádùn ẹlòmíràn tí nlo Ibi ìpamọ́ náà. Ìwọ kò gbọdọ̀ gbìyànjú láti wọlé láì gba àṣẹ sórí Ibi ìpamọ́ náà, sínú àwọn àkọọ́lẹ̀ mìíràn, sínú ẹ̀rọ tàbí nẹ́tíwọọ̀kì kọmputa tó ní àsopọ̀ pẹ̀lú apèsè Microsoft tàbí Ibi ìpamọ́ náà yòówù, nípasẹ̀ wíwọlé sínú àlàyé inú ẹ̀rọ láì gba àṣẹ, tàbí títú àlàyé inú ẹ̀rọ palẹ̀ láti rí àlàyé titun, tàbí ní ọ̀nà mìíràn yòówù. Ìwọ kò gbọdọ̀ gbà tàbí gbìyànjú láti gba ohunkóhun tàbí àlàyé yòówù nípasẹ̀ ọ̀nà yòówù tí a kò mọ̀ọ́mọ̀ gbé kalẹ̀ nípasẹ̀ Ibi ìpamọ́ náà. Ìwọ kò gbọdọ̀ lo Ibi ìpamọ́ náà ní ọ̀nà yòówù tó lè dí ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, èyí tó kan mímọ̀ọ́mọ̀ pa ènìyàn lára, èyí sì kan Microsoft pẹ̀lú. Ìwọ kò gbọdọ̀ pín àwọn ọjà, àlàyé tàbí ìpèsè yòówù tó ti inú Ibi ìpamọ́ náà wá káàkiri láti fi ṣòwò, o kò gbọdọ̀ tẹ̀ wọ́n jáde fún gbogbo ènìyàn, o kò gbọdọ̀ fúnni ní ìwé-àṣẹ lórí wọn, o kò sì gbọdọ̀ tà wọ́n.

3. Awọn Ohun tí O Pèsè fún Microsoft tàbí tí O Gbé Sórí Ibi ìpamọ́ náà. Microsoft kìí sọ pé òhun ni òhún ni àwọn ohun tí o pèsè fún Microsoft (àwọn èyí tó kan ìjábọ̀, àwọn ìgbéléwọ̀n, àtúnyẹ̀wò àti ìmọ̀ràn) tàbí àwọn ohun tí o ṣàfihàn wọn, tí o fi ṣọwọ́ sórí ayélujára, àwọn ọ̀rọ̀ tí o dá sí tàbí tí o firánṣẹ́ sí Ibi ìpamọ́ náà tàbí àwọn ìpèsè Microsoft tó níí ṣe pẹ̀lú rẹ̀, fún àtúnyẹ̀wò àwọn ẹlòmíràn (ọ̀kọ̀ọ̀kan èyí tó jẹ "Ìfàkalẹ̀" àti lápapọ̀ "Àwọn Ìfàkalẹ̀"). Ṣùgbọ́n, ìwọ fún Microsoft ní ẹ̀tọ́ láti lo Ìfàkalẹ̀ rẹ, láti yíipadà, láti múu yẹ fún ohun kan, láti ṣàtúndá rẹ̀, láti ṣẹ̀dá ohun mìíràn láti ara rẹ̀, láti túmọ rẹ̀ sí èdè mìíràn, láti ṣàtúnkọ rẹ̀, láti ṣeé, láti pín i káàkiri, àti láti fihàn, láìsí sísan owó àṣẹ oníṣẹ́, èyí tí yóò sì wà títí, tí kì yóò ṣeé fagilé, káàkiri àgbáyé, tí kò ní ìhámọ́ kankan, tí a sì lè fúnni ní ìwé-àṣẹ mìíràn fún, èyí tó sì kan orúkọ rẹ, lọ́nàkọnà yòówù. Bí o bá ṣe àgbéjáde Ìfakalẹ̀ rẹ ní àwọn abala Ibi ìpamọ́ náà níbití òun ti wà káàkiri ayélujára láìsí ìhámọ́, Ìfakalẹ̀ rẹ lè hàn nínú àwọn àfihàn tàbí ohun àmúlò tí a fi gbé Ibi ìpamọ́ náà lárugẹ àti/tàbí àwọn ọjà, ìpèsè àti àkóónú tí a ntà fúnni ní Ibi ìpamọ́ náà. Ìwọ ṣe ìlérí, o sì ṣe oníduro pé o ní (ìwọ yóò sì ní) gbogbo ẹ̀tọ́ tó yẹ fún ṣíṣe Ìfàkalẹ̀ yòówù tí o pèsè, àti láti fún Microsoft ní àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí.

Kì yóò sí sísan àsanpadà kankan lórí lílo Ìfàkalẹ̀ rẹ. Microsoft kò sí lábẹ́ ojúṣe kankan láti ṣe àfihàn tàbí láti lo Ìfàkalẹ̀ yòówù, Microsoft sì lè mú Ìfàkalẹ̀ yòówù kúrò nígbà yòówù nípa lílo làákàyè ti ara rẹ̀ níkan. Microsoft kò ní ojúṣe kankan, òun kò sì ní ẹjọ́ kankan láti dáhùn fún Ìfàkalẹ̀ rẹ tàbí àwọn ohun tí àwọn ẹlòmíràn ṣe àfihàn rẹ̀, tí wọ́n fi ṣọwọ́ sórí ayélujára, tí wọ́n fi lélẹ̀ tàbí firánṣẹ́ nípasẹ̀ Ibi ìpamọ́ náà.

Bí o bá ṣe ìdíwọ̀n dídára tàbí àtúnyẹ̀wò ohun èlò kan nínú Ibi ìpamọ́ kan, o lè gba ímeèlì láti ọwọ́ Microsoft, èyí tó ní àkóónú láti ọ̀dọ̀ olùgbéjáde ohun èlò náà nínú.

4. Àwọn Ìtọ́kasí Ààyè Ayélujára Àwọn Ẹlòmíràn. Ibi ìpamọ́ náà lè ní àwọn ìtọ́kasí ààyè ayélujára àwọn ẹlòmíràn tó lè mú kí o lọ kúrò ní Ibi ìpamọ́ náà. Àwọn ààyè tí a tọ́ka sí náà kò sí lábẹ́ ìṣàkóso Microsoft, bẹ́ẹ̀ sì ni Microsoft kọ́ ló ni ojúṣe fún àwọn àkóónú ààyè tí a tọ́ka sí yòówù tàbí ìtọ́kasí yòówù tó wà nínú ààyè kan tí a tọ́ka sí. Microsoft npèsè àwọn ìtọ́kasí wọ̀nyí fún ọ fún ìrọ̀rùn rẹ nìkan ni, bẹ́ẹ̀ sì ni níní ìtọ́kasí yòówù nínú wọn kò túmọ̀ sí pé Microsoft fọwọ́sí irú àwọn ààyè ayélujára bẹ́ẹ̀. Ìṣàmúlò ààyè ayélujára àwọn ẹlòmíràn rẹ lè wà lábẹ́ àwọn àdéhùn àti májẹ̀mú àwọn ẹlòmíràn náà.

Àwọn Àdéhùn tó níí ṣe Pẹ̀lú Títa Ọjà ÀTI ÀWỌN ÌPÈSÈ fún Ọ

5. Wíwà Káàkiri Agbègbè. Àwọn ọjà àti ìpèsè tó wà lè yàtọ̀, èyí sì dá lórí agbègbè àti ẹ̀rọ rẹ. Ní àfikún, ìhámọ́ lè wà nípa àwọn ibití a lè fi àwọn ọjà ránṣẹ́ sí, gẹ́gẹ́ bí a ti gbée kalẹ̀ nínú àwọn ìlànà ìfọjàránṣẹ́ wa. Láti parí ọjà rírà rẹ, a lè fẹ́ kí o ní àdírẹ́ẹ̀sì ìfìwéowó-ránṣẹ́sí àti ti ìfọjà-ránṣẹ́sí tó fẹsẹ̀múlẹ̀ láàárín orílẹ̀-èdè tàbí agbègbè Ibi ìpamọ́ náà tí o tí nrajà.

6. Àwọn Aṣàmúlò Ìkẹyìn Nìkan. Ìwọ gbọ́dọ̀ jẹ́ aṣàmúlò ìkẹyìn láti ra ọjà àti ìpèsè láti Ibi ìpamọ́ náà. Àwọn àaláàtúntà kò ní ẹ̀tọ́ láti rajà.

7. Ìhámọ́ nípa Gbígbé ọjà lọ sí ìlẹ̀ òkèèrè. Àwọn ọjà àti ìpèsè tí a rà láti Ibi ìpamọ́ náà lè wà lábẹ́ òfin àti ìlànà ìṣàkóso gbígbé ọjà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fún títà àti ti àwọn aṣọ́bodè. O gbà láti bọ̀wọ̀ fun gbogbo òfin àti ìlànà ilẹ̀ òkèèrè àti ti ìlú ẹni tí ó yẹ.

8. Ìdíyelé. Nípa pípèsè ìlànà owó-sísan fún Microsoft, ìwọ: (i) fihàn pé o ní àṣẹ láti lo ìlànà owó sísan náà tí o pèsè, àti pé àlàyé owó sísan yòówù tí o pèsè jẹ́ òtítọ́, ó sì pé; (ii) fún Microsoft ní àṣẹ láti díyelé ọ fún àwọn ọjà, ìpèsè tàbí àkóónú tó wà tí o rà, nípa lílo ìlànà owó sísan rẹ; àti (iii) fún Microsoft ní àṣẹ láti díyelé ọ fún àfidámọ̀ Ibi ìpamọ́ náà yòówù tí a nsanwó fún, èyítí ìwọ yàn láti forúkọsílẹ̀ fún tàbí láti lò. O gbà láti tètè mú àkọọ́lẹ̀ rẹ àti àwọn àlàyé rẹ mìíràn dójú ìwọ̀n, èyí sì kan àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì rẹ àti nọ́mbà àti déètì ìparí-iṣẹ́ káàdì ìsanwó rẹ, kí a bá a lè parí iṣẹ́ lórí ìbánidòwòpọ̀ rẹ, kí a sì kàn sí ọ bí ó ti yẹ nípa ìbánidòwòpọ̀ rẹ. Àwa lè díyelé ọ (a) ṣáájú ohun tí o fẹ́ rà; (b) ní àkókò ọjà-rírà; (c) lọ́gán lẹ́yìn ọjà-rírà; tàbí (d) láti ìgbà dé ìgbà fún ṣíṣe aláàbápín. Bákan náà a tún lè díyelé ọ tó iye owó tí o ti fọwọ́ sí, àwa yóò sì sọ fún ọ ṣáájú àti ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àdéhùn ṣíṣe aláàbápín rẹ, nípa àyípadà yòówù nínú iye owó tí a ó yọ fún ṣíṣe aláàbápín rẹ, èyí tí nwáyé láti ìgbà dé ìgbà. Àwa lè díyelé ọ nígbà kan náà fún iye àkókò ìdíleyé ìṣáájú tó ju ọ̀kan lọ fún àwọn owó tí a kò tètè ṣiṣẹ́ lé lórí. Wo abala Ìsọdọ̀tun Àìfọwọ́yí nísàlẹ̀ yìí.

Bí o bá nkópa nínú ìpèsè àkókò ìdánwò yòówù, o gbọ́dọ̀ fagilé ìpèsè náà ní òpin àkókò ìdánwò náà láti dènà gbígba àfikún ìdíyelé titun, àfi bí a bá sọ ohun mìíràn fún ọ. Bí o kò bá fagilé ìpèsè náà ní òpin àkókò ìdánwò náà, ìwọ fún wa ní àṣẹ láti gba owó náà nípasẹ̀ ìlànà owó-sísan rẹ fún ọjà tàbí ìpèsè náà.

9. Owó Sísan Láti Ìgbà Dé Ìgbà. Nígbà tí o bá ra àwọn ọjà, ìpèsè tàbí àkóónú tó jẹ́ fún ṣíṣe aláàbápín (bí àpẹẹrẹ, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, oṣooṣù, oṣooṣù mẹta mẹta, tàbí ọdọọdún (bí ó bá ti tọ́)), o gbà pé ìwọ nfún ni ní àṣẹ fún owó sisàn láti ìgbà dé ìgbà, a ó sì san owó fún Microsoft nípasẹ̀ ìlànà owó sísan tí o yàn láàárín àwọn àkókò àtìgbàdégbà náà tí o yàn, títí di ìgbà tí ìwọ tàbí Microsoft bá mú ṣíṣe aláàbápín náà dópin tàbí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àdéhùn rẹ̀. Nípa fífún ni ní àṣẹ fún owó sísan láti ìgbà dé ìgbà, ìwọ nfún Microsoft ní àṣẹ láti ṣiṣẹ́ lórí irú owó sísan bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìlànà iṣẹ́ ẹ̀rọ fún gbígbé owó láti ibi kan sí òmíràn, tàbí bíi ìwé sọ̀wédowó tí a ti sanwó si láti inú ibi ìpamọ́ owó rẹ tí o yàn (bí ó bá jẹ́ Ilé Ìfúnniláṣẹ owó (Automated Clearing House) tàbí irú owó sísan bẹ́ẹ̀), tàbí gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé sínú ibi ìpamọ́ owó rẹ (bí ó bá jẹ́ Kírẹ́dítí kaàdì tàbí owó sísan bẹ́ẹ̀) (lápapọ̀, "Owó Sísan Pẹ̀lú Ẹ̀rọ"). A má a nsábà díyeléni ṣáájú fún àkókò tí a ó fi ṣe aláàbápín. Bí a bá dá owó kan tó yẹ fún sisan pada láìsan tàbí bí a bá kọ káàdì ìyáwó tàbí irú owó sísan bẹ́ẹ̀, Microsoft tàbí àwọn olupèsè iṣẹ́ rẹ̀ ní ẹ̀tọ́ láti gba irú ohun tí a dá padà bẹ́ẹ̀, ohun tí a kọ̀ tàbí àwọn owó mìíràn bí òfin tó yẹ bá ṣe gbaniláàyè sí.

10. Wíwà Ọjà àti Òṣùwọ̀n àti Iye Ọjà tàbí Ìpèsè tí a lè Béèrè fún. Àwọn iye owó ọjà ati rírí ọjà kan rà lè yípadà nígbà yòówù, láì sọ fún ẹnikẹ́ni. Microsoft lè fi ìwọ̀n sí iye ohun tí a lè rà lẹ́ẹ̀kanṣoṣo nígbà tí a bá bèèrè fún ọjà tàbí ìpèsè, pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ kan, pẹ̀lú káàdì ìsanwó kan, fún ẹnìkan, tàbí ìdílé kan. Bí àwọn ọjà tàbí ìpèsè tí o béèrè fún kò bá sí, a lè kàn sí ọ láti fi àwọn ọjà mìíràn tí o lè yàn lọ̀ ọ́. Bí o kò bá yàn láti ra ọjà mìíràn náà, àwa yóò fagilé ìbéèrè fún ọjà rẹ.

Microsoft lè kọ ìbéèrè fún ọjà rẹ nígbà yòówù, kó sì dá owó yòówù tí o ti san fún ọjà náà padà, fún àwọn èrèdí tó lè jẹ mọ́, ṣùgbọ́n tí kò parí sí, bí o kò bá tíì kojú ìwọ̀n àwọn àdéhùn tí a gbé kalẹ̀ lásìkò tí o bèèrè fún ọjà náà, bí a kò bá lè ṣiṣẹ́ lórí owó-sísan rẹ, bí àwọn ọjà àti ìpèsè tí o bèèrè fún kò bá sí nílẹ̀, tàbí fún àṣìṣe nínú iye owó ọjà tàbí àṣìṣe mìíràn. Bí ó bá jẹ́ pé àṣìṣe wáyé nípa iye owó ọjà tàbí ní ọ̀nà mìíràn, àwa ní ẹ̀tọ́, pẹ̀lú làákàyè wa, yálà láti (a) fagilé ìbéèrè fún ọjà rẹ tàbí ọjà tí o rà tàbí (b) kàn sí ọ fún ìtọ́sọ́nà. Bí fífagilé ọjà bá wáyé, a ó sọ ànfàní àti wọlé sí àkóónú tó níí ṣe pẹ̀lú rẹ̀ di àìlèṣiṣẹ́.

A lè sọ ànfàní àti wọlé sí àkóónú tó níí ṣe pẹ̀lú àkọọ́lẹ̀ rẹ di àìlèṣiṣẹ́ fún èrèdí yòówù. A tún lè yọ àwọn eré, ohun èlò, àkóónú, tàbí ìpèsè kúrò lórí ẹ̀rọ rẹ, tàbí kí á mú wọn má ṣiṣẹ́, kí a lè dáàbòbo Ibi ìpamọ́ náà tàbí àwọn ẹnití ohun náà ní ipa lórí wọn lásìkò náà. Àwọn àkóónú àti ohun èlò kan lè má wà láti ìgbà dé ìgbà tàbí kí a tà wọ́n fún àkókò ránpẹ́. Agbègbè lè ní ipa lórí wíwà ọjà. Nítorí náà, bí o bá yí àkọọ́lẹ̀ tàbí ẹ̀rọ rẹ padà sí agbègbè mìíràn, o lè má lè tún àkóónú tàbí àwọn ohun èlò gbé wálẹ̀ láti ayélujára tàbí kí o tún àwọn àkóónú kan tí o rà ṣàn wọlé; o lè nílò láti tún àkóónú tàbí àwọn ohun èlò náà tí o ti sanwó fún ní agbègbè rẹ àtijọ rà. Àfi títí dé ibití òfin tó yẹ bèèrè dé, àwa kò ní ojúṣe kankan láti pèsè àtún-gbéwálẹ̀ láti ayélujára tàbí rírọ́pò àkóónú tàbí àwọn ohun èlò yòówù tí o rà.

11. Àwọn Ìmúdójúìwọ̀n. Bí ó bá yẹ bẹ́ẹ̀, Microsoft yóò ṣàyẹ̀wò láìfọwọ́yí fún àwọn ìmúdójúìwọ̀n, yóò sì gbé wọn wálẹ̀ sórí àwọn ohun èlò rẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò buwọ́lù wọlé sí Ibi ìpamọ́ náà. O lè yí àwọn ètò Ibi ìpamọ́ tàbí ẹ̀rọ rẹ padà bí o kò bá fẹ́ má a gba àwọn ìmúdójúìwọ̀n láìfọwọ́yí sórí àwọn ohun èlò Ibi ìpamọ́. Ṣùgbọn, àwọn ohun èlò Ibi ìpamọ́ Office kan tó wà lórí ayélujára pátápátá tàbí fún ìgbà díẹ̀ ni a lè mú dójú ìwọ̀n nígbà yòówù nípasẹ̀ olùgbéjáde ohun èlò náà, wọ́n sì lè má nílò àṣẹ rẹ láti mú wọn dójú ìwọ̀n.

12. Àwọn Ìwé-Àṣẹ àti Ẹ̀tọ́ Ìṣàmúlò Ẹ̀yà Àìrídìmú. Ẹ̀yà àìrídìmú àti àkóónú oní-díjítàlì mìíràn tí a pèsè nípasẹ̀ Ibi ìpamọ́ náà ni a fún ọ ní ìwé-àṣẹ fún, a kò tà wọ́n fún ọ. Àwọn ohun èlò tí o gbé wálẹ̀ tààrà láti Ibi ìpamọ́ náà wà lábẹ́ Àwọn Àdéhùn Ìwé-àṣẹ Ohun Èlò Déédé ("SALT") èyí tó wà ní [https://go.microsoft.com/fwlink/p/?linkid=838610&clcid=0x046a], àfi bí a bá pèsè ìwé-àṣẹ mìíràn pẹ̀lú ohun èlò náà. (Àwọn ohun èlò tí o gbé wálẹ̀ láti Ibi ìpamọ́ Office ni a kò darí nípasẹ̀ SALT náà, àwọn sì ní ìwé-àṣẹ ọ̀tọ̀ tó kàn wọ́n.) Àwọn ohun èlò, eré àti àkóónú oní-díjítàlì mìíràn tí o gbà nípasẹ̀ Ibi ìpamọ́ náà wà lábẹ́ àwọn òfin ìṣàmúlò tó wà ní https://go.microsoft.com/fwlink/p/?LinkId=723143. Ó yé ọ, o sì gbà pé àwọn ẹ̀tọ́ rẹ nípa àwọn ọjà oní-nọ́mbà ní àhámọ́ nípasẹ̀ Àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí, àwọn òfin ẹ̀tọ́ ọjà-títà àti àwọn òfin ìṣàmúlò tí a mẹ́nubà lókè yìí. Àwọn ìwé-àṣẹ tí o rà ní Ibi ìpamọ́ Aláàlétà ti Microsoft wà lábẹ́ ìfohùnṣọ̀kan ìwé-àṣẹ tó bá ẹ̀yà àìrídìmú náà wá, ìwọ yóò sì nílò láti faramọ́ ìfohùnṣọ̀kan ìwé-àṣẹ náà nígbàtí o bá fi ẹ̀yà àìrídìmú náà sórí ẹ̀rọ. Ṣíṣẹ̀dá tàbí àtúnpín ẹ̀yà àìrídìmú tàbí ọjà yòówù tí kò sí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àdéhùn ìwé-àṣẹ, àwọn òfin ìṣàmúlò àti òfin tó yẹ, jẹ́ ohun tí a fi òfin dé pàtàpàtà, ó sì lè fa ìjìyà abẹ́lé tàbí tí ọ̀daràn tó burú púpọ̀. Àwọn arúfin yìí wà lábẹ́ ewu ìbániṣẹjọ́ títí dé ibití òfin fi ààyè gbani dé.

JỌ̀WỌ́ KÀN SÍ IBI ÌPAMỌ́ ALÁÀLÉTÀ TI MICROSOFT (BÍ A TI ṢÀLÀYÉ NÍ ABALA ÀWỌN ÀKÍYÈSI ÀTI ÌBÁNISỌ̀RỌ̀ NÍSÀLẸ̀ YÌÍ) BÍ O BÁ FẸ́ Ẹ̀DÀ ÌFOHÙNṢỌ̀KAN ÌWÉ-ÀṢẸ TÓ YẸ FÚN Ẹ̀YÀ ÀÌRÍDÌMÚ TÍ A FI SÍNÚ PÀLÍ, LÁÌSANWÓ, KÍ O TÓ ṢÍ PÁLÍ Ẹ̀YÀ ÀÌRÍDÌMÚ YÒÓWÙ.

ÀWỌN ÀDÉHÙN ÀTI MÁJẸ̀MÚ MÌÍRÀN. Ní àfikún sí ẹ̀yà àìrídìmú àti àwọn ọjà mìíràn tó ṣeé gbé wálẹ̀ láti ayélujára, àwọn ọjà àti ìpèsè mìíràn tó wà fún rírà tàbí dídánwò ní Ibi ìpamọ́ náà ni a lè filọ̀ ọ́ lábẹ́ àwọn ìfohùnṣọ̀kan ìwé-àṣẹ aṣàmúlò ìkẹyìn, àwọn àdéhùn ìṣàmúlò, àwọn àdéhùn ìpèsè, tàbí àwọn àdéhùn àti májẹ̀mú mìíràn tó yàtọ̀. Bí o bá ra tàbí lo àwọn ọjà wọ̀nyí, a tún lè ní kí o fọwọ́sí àwọn àdéhùn náà gẹ́gẹ́ bí ara àgbékalẹ̀ fún rírà, fífi sórí ẹ̀rọ, tàbí ṣíṣàmúlò.

FÚN ÌRỌ̀RÙN RẸ, MICROSOFT A MÁ A PÈSÈ, GẸ́GẸ́ BÍ ARA IBI ÌPAMỌ́ TÀBÍ ÀWỌN ÌPÈSÈ NÁÀ, TÀBÍ NÍNÚ Ẹ̀YÀ ÀÌRÍDÌMÚ TÀBÍ ỌJÀ RẸ̀, ÀWỌN IRIN-IṢẸ́ ÀTI OHUN ÈLÒ FÚN ÌṢÀMÚLÒ ÀTÍ/TÀBÍ GBÍGBÉWÁLẸ̀ TÍ KÌÍ ṢE ARA ỌJÀ TÀBÍ ÌPÈSÈ TÍ A TÀ. TÍTÍ DÉ IBITÍ ÒFIN TÓ YẸ FI ÀÀYÈ GBANI DÉ, MICROSOFT KÒ ṢE ÌLÉRÍ KANKAN YÒÓWÙ, ÀTÌLẸ́YÌN TÀBÍ ÌFINILỌ́KÀNBALẸ̀ NÍPA ÌṢEDÉÉDÉ ÀWỌN ÀBÁJÁDE TÀBÍ ÀGBÉJÁDE LÁTI IRÚ ÀWỌN IRIN-IṢẸ́ TÀBÍ OHUN ÈLÒ YÒÓWÙ NÁÀ.

Jọ̀wọ́ bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹ̀tọ́ ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ àwọn ẹlòmíràn nígbàtí o bá nlo àwọn irin-iṣẹ́ àti ohun èlò náà tí a pèsè nípasẹ̀ Ibi ìpamọ́ náà, tàbí nínú ẹ̀yà àìrídìmú tàbí ọjà.

13. Àwọn Kóòdù fún Ẹ̀yà àìrídìmú àti Àwọn Àgbéwálẹ̀ Àkóónú. Àwọn ẹ̀yà àìrídìmú àti àkóónú kan ni a má a nfi jíṣẹ́ fún ọ nípasẹ̀ fífi ìtọ́kasí àgbéwálẹ̀ sínú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ tí a mọ̀ pẹ̀lú ọjà tí o rà. Ní ìbámu pẹ̀lú abala tó wà nísàlẹ̀ yìí, àwa a má a fi ìtọ́kasí àgbéwálẹ̀ náà pẹ̀lú kọ́kọ́rọ́ oní-díjítàlì tó yẹ fún àwọn ìrajà wọ̀nyí pamọ́ sínú àkọọ́lẹ̀ Microsoft rẹ fún ọdún mẹta lẹ́yìn ọjọ́ tí o ra ohun náà, ṣùgbọ́n a kò ṣe ìlérí àti tọ́jú wọn fún iye àsìkò kan pàtó. Fún àwọn ọjà tí à nṣe aláàbápín fún, èyí tí a nfi jíṣẹ́ nípa pípèsè ìtọ́kasí àgbéwálẹ̀, àwọn àdéhùn ọ̀tọ̀ àti ẹ̀tọ́ ìpamọ́ lè wáyé, àwọn èyítí ìwọ yóò lè ṣàtúnyẹ̀wò wọn, kí o sì faramọ́ wọn lásìkò ìṣaláàbápín rẹ.

O gbà pé a lè fagilé tàbí ṣàtúnṣe sí ètò ìpamọ́ kọ́kọ́rọ́ oní-díjítàlì wa nígbà yòówù. O tún gbà pé a lè dẹ́kun ṣíṣe àtìlẹ́yìn fún fífi kọ́kọ́rọ́ pamọ́ fún ọjà kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà yòówù àti fún èrèdí yòówù, èyítí ó kan, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, ní òpin àkókò àtìlẹ́yìn ọjà náà, lẹ́yìn tí ìwọ kì yóò ní ànfàní àti wọlé sí ìtọ́kasí àgbéwálẹ̀ tàbí kọ́kọ́rọ́ oní-díjítàlì náà mọ́. Bí a bá fagilé tàbí ṣàtúnṣe sí ètò wa tí yóò fi jẹ́ pé ìwọ kì yóò ní ànfàní àti wọlé sí ìtọ́kasí àgbéwálẹ̀ tàbí (àwọn) kọ́kọ́rọ́ oní-díjítàlì inú àkọọ́lẹ̀ rẹ mọ́, àwa yóò pèsè ìkìlọ̀ fún ọ, ní, ó kéré, ọjọ́ 90 ṣáájú àkókò náà, nípasẹ̀ àlàyé tí a fí nkàn sí ọ fún àkọọ́lẹ̀ Microsoft tí èyí kàn náà.

14. Iye owó ọjà. Bí a bá ní Ibi ìpamọ́ Aláàlétà Microsoft ní orílẹ̀-èdè tàbí agbègbè rẹ, àwọn iye owó ọjà, àṣàyàn ọjà àti àwọn ìgbélárugẹ àwọn ọjà tí a pèsè níbẹ̀ lè yàtọ̀ sí ti àwọn Ibi ìpamọ́ orí ayélujára. Títí dé ibití òfin tó yẹ fi ààyè gbani dé, Microsoft kò ṣe àtìlẹ́yìn pé iye owó ọjà kan, ọjà kan tàbí ìgbélérugẹ ọjà kan tí a pèsè lórí ayélujára yóò wà bákan náà tàbí pé a ó ṣe bákan náà ní Ibi ìpamọ́ Aláàlétà Microsoft, tàbí ní ìdàkejì èyí.

Ibi ìpamọ́ náà kò ní àtìlẹ́yìn dídọ́gba iye owó ọjà kan náà. Àwa kì yóò mú iye owó ọjà tí àwọn aláàlétà mìíràn kéde fún irú ọjà kan náà dọ́gba pẹ̀lú tiwa.

A lè pèsè àṣàyàn láti bèèrè fún àwọn ọjà kan ṣáájú ọjọ́ tí wọn yóò wà fún títà. Láti ní ìmọ̀ síwájú síi nípa àwọn ìlànà bíbèèrè fún ọjà ṣáájú àkókò tí yóò wà fún títà, jọ̀wọ wo Ojú-ìwé bíbèèrè fún ọjà ṣáájú àkókò tí yóò wà fún títà wa https://go.microsoft.com/fwlink/p/?linkid=834935&clcid=0x046a.

Àfi bí a bá sọ ohun mìíràn, àwọn iye owó ọjà tí a fihàn ní Ibi ìpamọ́ náà kò kan àwọn owó ìlú tàbí àwọn owó ("Àwọn owó ìlú") tí a ngbà tó lè kan ọjà rírà rẹ. Àwọn iye owó ọjà tí a fihàn ní Ibi ìpamọ́ náà kò kan àwọn owó ìfijíṣẹ́ pẹ̀lú. Awọn owó ìlú àti owó ìfijíṣẹ́ (bí ó ṣe tọ́) ni a ó fikún iye owó ohun tí o rà, a ó sì fihàn ní ojú-ìwé ibití o ti fẹ́ sanwó. Ìwọ nìkan ni ó ni ojúṣe fún sísan irú Àwọn Owó ìlú àti iye owó bẹ́ẹ̀.

Àwọn ìbánidòwòpọ̀ kan lè nílò ìṣàyípadà owó ilẹ̀ òkèèrè tàbí kí wọ́n nílò iṣẹ́ ṣíṣe síwájú síi ní orílẹ̀-èdè mìíràn, èyí sì dá lórí ipò ibití ìwọ wà. Ilé ìfowópamọ́ rẹ lè bèèrè fún àfikún owó fún àwọn iṣẹ́ náà bí o bá lo káàdì kírẹ́díìtì tàbí dẹ́bíìtì. Jọ̀wọ́ kàn sí ilé ìfowópamọ́ rẹ fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé.

15. Àṣàyàn Ìsọdọ̀tun Àìfọwọ́yí. Bí o bá jẹ́ pé a gba ni láàyè láti ṣe ìsọdọ̀tun àìfọwọ́yí ní orílẹ̀-èdè, agbègbè, àdúgbò/àlà ilẹ̀ rẹ, tàbí ní ìpínlẹ̀ rẹ, o lè yàn pé kí àwọn ọjà tàbí ìpèsè má a sọ ara wọn dọ̀tun láìfọwọ́yí lẹ́yìn àkókò ipèsè kan pàtó. Bí o bá yàn láti má a sọ awọn ọjà tàbí ìpèsè rẹ náà dọ̀tun láìfọwọ́yí, àwa lè sọ àwọn ọjà tàbí ìpèsè rẹ dọ̀tun láìfọwọ́yí ní òpin àkókò ìpèsè tí nlọ lọ́wọ́ náà, kí a sì gba iye owó tó yẹ ní àkókò náà fún àkókò tí ìsọdọ̀tun náà yóò fi wà, àfi bí o bá ti yàn láti fagilé ọjà tàbí ìpèsè náà bí a ti ṣe àlàyé nísàlẹ̀ yìí. Àwa yóò díyelé ìlànà owó sísan tí o yàn fún ìsọdọ̀tun náà, yálà ó ti wà nílẹ̀ ní ọjọ́ ìsọdọ̀tun náà tàbí o pèsè rẹ̀ lẹ́yìn náà. O lè fagilé àwọn ọjà tàbí ìpèsè náà kí ó tó di ọjọ́ ìsọdọ̀tun náà. O gbọdọ fagilé wọn kí ó tó di ọjọ́ ìsọdọ̀tun bí o kò bá fẹ kí a díyelé ọ fún sọdọ̀tun náà.

16. Ìlànà Ìdápadà. Àwa yóò gba àwọn ìdápadà àti pàṣípààrọ̀ padà fún irú ọjà tó bá yẹ fún ọjọ́ 14 days láti ọjọ́ tí o ti ra ọjà náà tàbí tí o ti gbée wálẹ̀ láti ayélujára, bí ó bá ṣe tọ́. Ṣá ti dá ọjà tí èyí kàn náà padà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà ní titun, nínú pálí tí a fi tàá, pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀, àwọn ìwé ìtọ́nisọ́nà àti àwọn ìwé mìíràn tí a fi sínú rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀. Ìlànà Àsanpadà yìí kò kan ẹ̀tọ́ yòówù lábẹ́ òfin tó lè ní ipa lórí ohun tí o rà.

Àwọn ẹ̀yà àìrídìmú àti eré tí a fi sínú pálí ni o gbọ́dọ̀ dá padà bí a ṣe lẹ̀ wọ́n pa, gbogbo àwọn ohun inú rẹ̀ àti kọ́kọ́rọ́ ọjà inú rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ara ìyọkúrò tó níwọ̀n, àwọn ẹ̀yà àìrídìmú àti eré tí a ti ṣí pálí wọn ni a lè dá padà láàárín àkókò ìdápadà wọn, bí o kò bá faramọ́ ìfohùnṣọ̀kan ìwé-àṣẹ wọn, ṣùgbọ́n àfi bí o kò bá tíì ṣe ẹ̀dà tàbí lo ẹ̀dà wọn yòówù nìkan ni.

Àwọn ohun kan wà tí kò kún ojú òṣùwọ̀n fún dídápadà; àfi bí òfin tàbí ìfilọ̀ ìpèsè kan pàtó bá sọ ohun mìíràn, gbogbo rírà irú àwọn ọjà bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun àṣeparí, kò sì sí àsanpadà:

àwọn ohun èlò oní-díjítàlì, àwọn eré, àkóónú àti ìṣaláàbápín inú ohun èlò, àwọn orin, sinimá, ìfihàn amóhùnmáwòrán, àti àwọn àkóónú tó níí ṣe pẹ̀lú wọn;

àwọn káàdì ẹ̀bùn àti àwọn káàdì ìpèsè/ìṣaláàbápín (bí àpẹẹrẹ, Skype, Xbox Live, Groove Music Pass);

àwọn ọjà tí a ti fi ṣe ti ara ẹni tàbí tí a ṣe ní àkànṣe fún ẹnìkan;

àwọn ọjà tí a bèèrè fún ní pàtàkì, bí wọn kì bá nṣe lára àwọn ìfilọ̀ ìgbélárugẹ Ibi ìpamọ́ kan;

àwọn ọjà ibi ìpamọ́ tí a nwọlé sí láìròtẹ́lẹ̀ ("RAM");

àwọn ìpèsè tí a ti ṣe tàbí tí a lò; àti

àwọn ohun tí a tà ní gbànjo láti mú ilé-ìtajà ṣófo tàbí àwọn tí a sààmìsí bíi "Ìtajà Ìkẹyìn" tàbí "Àìṣeédápadà".

Nígbàtí o bá dá ohun tó kún ojú òṣùwọ̀n fún dídápadà padà, àwa yóò san iye owó náà lẹkunrẹrẹ, lẹ́yìn tí a ti yọ iye owó ìfijíṣẹ́ àti ti àbójútó (bí èyí bá wà), ìwọ yóò sì gba àsanpadà rẹ, nígbà púpọ̀, láàárín ọjọ́ iṣẹ́ 3-5. A ó lo àkọọ́lẹ̀ kan náà fún àwọn àsanpadà yòówù, àti nípa lílo ìlànà ìsanwó kan náà, èyítí o lò láti fi béèrè fún ọjà náà (àfi bí o bá yan kírẹ́díìtì Ibi ìpamọ́ kan ní iye owó àsanpadà náà).

Fún àlàyé lẹkunrẹrẹ nípa bí a tí ndá àwọn ọjà tó bá kún ojú òṣùwọ̀n padà, wo Ojú-ìwé Àwọn Ìdápadà àti Àsanpadà wa https://go.microsoft.com/fwlink/p/?linkid=723276&clcid=0x046a.

Bí o bá ngbé ní Taiwanu, jọ̀wọ́ ṣàkíyèsi pé, ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Ìdáàbòbò Aṣàmúlò Ìkẹyìn ti Taiwanu àti ti àwọn ìlànà tó yẹ, ọjà-rírà tó níí ṣe pẹ̀lú àkóónú díjítàlì, èyí tí a pèsè nípasẹ̀ ohun àìrídìmú àti/tàbí àwọn iṣẹ́ orí ayélujára, jẹ́ àṣekẹ́yìn, kò sì sí àsanpadà bí a bá pèsè irú àkóónú tàbí iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lórí ayélujára. O kò ní ẹ̀tọ́ láti bèèrè fún àkókò ìsinmi yòówù tàbí àsanpadà yòówù.

17. Owó Sísan fún Ọ. Bí a bá jẹ ọ ní owó kan, o gbà láti pèsè àlàyé yòówù tí a nílò láti fún ọ ní owó náà lásìkò àti lẹkunrẹrẹ. Ìwọ ni ó ni ojúṣe fún owó ìlú àti àwọn owó tó wà fún sísan tó lè wáyé nípasẹ̀ sísan owó yìí fún ọ. Títí dé ibití òfin tó yẹ fi ààyè gbani dé, o tún gbọ́dọ̀ tẹ̀lé àwọn òfin mìíràn yòówù tí a gbé lé ẹ̀tọ́ rẹ sí owó sísan yòówù. Bí a bá ṣèṣì san owó kan fún ọ ní àṣìṣe, a lè yọọ́ padà tàbí kí a bèèrè pé kí o dáa padà. O gbà láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wa nínú akitiyan wa láti ṣe èyí. A tún lè dín owó tí a ó san fún ọ kù láì sọ fún ọ, láti ṣàtúnṣe sí owó tí a bá ti san kọjá iye tó yẹ kí a san fún ọ tẹ́lẹ̀ rí.

18. Àwọn Káàdì Ẹ̀bùn. Àwọn káàdì ẹ̀bùn tí a rà ní Ibi ìpamọ́ Aláàlétà ti Microsoft ni Ìfohùnṣọ̀kan Káàdì Ẹ̀bùn Aláàlétà ndarí, èyí sì wà ní https://www.microsoftstore.com/store/msusa/html/pbPage.Help_Retail_Stores#GiftCards.

Àlàyé nípa àwọn káàdì ẹ̀bùn Skype wà ní ojú-ìwé Ìrànlọ́wọ́ Skype (https://support.skype.com/en/faq/FA12197/what-is-a-skype-gift-card-and-where-can-i-buy-one).

Ìràpadà àti ìmúlò àwọn káàdì ẹ̀bùn Microsoft mìíràn ni Àwọn Àdéhùn àti Ìlànà Káàdì Ẹ̀bùn Microsoft ndarí (https://commerce.microsoft.com/PaymentHub/Help/Show/toc_link_no_62).

19. Ìpèsè Oníbàárà. Jọ̀wọ́ lọ sí Ojú-ìwé Ìtajà àti Àtìlẹ́yìn https://go.microsoft.com/fwlink/p/?linkid=824761&clcid=0x046a fún àlàyé síwájú síi nípa àwọn àṣàyàn ìpèsè oníbàárà.

ÀWỌN ÀDÉHÙN GBOGBOGBÒ

20. Yíyí Àwọn Àdéhùn Padà. Microsoft lè yí Àwọn Àdéhùn Ìtajà náà padà nígbà yòówù, láì sọ fún ọ. Àwọn Àdéhùn Ìtajà tó wà nílẹ̀ ní àsìkò tí o bèèrè fún ọjà rẹ ni yóò darí ìrajà rẹ, tí yóò sì dúró bíi àdéhùn ìrajà láàárín wa. Kí o tó tún ra ọjà nígbà mìíràn, Microsoft lè ti yí Àwọn Àdéhùn Ìtajà náà padà láì sọ fún ọ. Jọ̀wọ́ ṣàtúnyẹ̀wò Àwọn Àdéhùn Ìtajà náà ní gbogbo ìgbà tí o bá lọ sí Ibi ìpamọ́ náà. A gbà ọ́ nímọ̀ràn láti fi ẹ̀dà Àwọn Àdéhùn Ìtajà náà pamọ́, tàbí kí o tẹ̀ẹ́ sínú ìwé fún kíkà lọ́jọ́ iwájú nígbàtí o bá rajà.

21. Ìhámọ́ nípa Ọjọ́-orí. Ìhámọ́ nípa ọjọ́-orí lè kan bí o ṣe nlo Ibi ìpamọ́ náà, èyí tó kan ìrajà.

22. Ohun Ìkọ̀kọ̀ àti Ìdáàbòbo Àlàyé Ara ẹni. Ìpamọ́ rẹ ṣe pàtàkì sí wa. A nlo àwọn àlàyé kan tí a gbà lọ́wọ́ rẹ láti fi ṣàkóso àti láti fi pèsè Ibi ìpamọ́ náà. Jọ̀wọ́ ka Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ Microsoft bí ó ti ṣe àlàyé irú àwọn détà tí à ngbà láti ọ̀dọ̀ rẹ àti láti inú àwọn ẹ̀rọ rẹ ("Détà") àti bí a ṣe nlo Détà rẹ. Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ náà tún ṣe àlàyé bí Microsoft ṣe nlo àkóónú rẹ, èyí tí ó jẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn; àwọn àfihàn tàbí èsì aṣàmúlò tí ìwọ fi ránṣẹ́ sí Microsoft nípasẹ̀ Ibi ìpamọ́ náà; àti àwọn fáìlì, fọ́tò, àkọsílẹ̀, ohùn, àwọn iṣẹ́ díjítàlì, àti àwọn fidio tí o gbé lọ sókè, tí o fipamọ́, tàbí tí o ṣàjọpín lórí àwọn ẹ̀rọ rẹ nípasẹ̀ Ibi ìpamọ́ náà("Àkóónú Rẹ"). Nípa lílo Ibi ìpamọ́ náà, o faramọ́ gbígbàjọ tí Microsoft ngba àwọn Àkóónú àti Détà Rẹ jọ, lílò wọ́n, àti ṣíṣàfihàn wọn, tààrà, bí a ti ṣe àlàyé rẹ̀ nínú Gbólóhùn Ìkọ̀kọ̀ náà.

23. Ìṣàfihàn àti Àwọ̀ Ọjà. Microsoft a má a gbìyànjú láti ṣe àfihàn àwọ̀ àti àwòrán ọjà bí wọ́n ṣe rí gangan, ṣùgbọ́n a kò lè sọ dájú pé àwọ̀ tí o rí lórí fèrèsé ìbòjú ẹ̀rọ rẹ yóò bá àwọ̀ ọjà náà gangan dọ́gba.

24. Àwọn Àṣìṣe nínú àfihàn Ibi ìpamọ́. À nṣiṣẹ́ takuntakun láti tẹ àlàyé jáde ní pípé, láti mú Ibi ìpamọ́ náà dójú ìwọ̀n láti ìgbà dé ìgbà, àti láti ṣàtúnṣe sí àwọn àṣìṣe tí a bá rí. Ṣùgbọ́n, èyíkéèyí nínú àkóónú tó wà ní Ibi ìpamọ́ náà lè má jẹ́ pípé tàbí kí wọ́n má ba ìgbà mú mọ́ ní àkókò kan pàtó. A ní ẹ̀tọ́ láti ṣàtúnṣe sí Ibi ìpamọ́ náà nígbà yòówù, èyí tí ó kan àwọn iye owó ọjà, oríṣi ọjà, ìfilọ̀ ọjà àti wíwà ọjà.

25. Ìfòpinsí Ìṣàmúlò tàbí Wíwọlé. Microsoft lè fòpinsí àkọọ́lẹ̀ rẹ tàbí ìṣàmúlò Ibi ìpamọ́ náà nígbà yòówù, fún ìdí yòówù, èyí tó kàn, láìsí ìhámọ́, bí o bá lòdì sí òfin Àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí tàbí ti Àwọn Ìlànà Ibi ìpamọ́ náà, tàbí bí Microsoft kò bá ṣàkóso Ibi ìpamọ́ náà mọ́. Nípa lílo Ibi ìpamọ́ náà, o gbà pé ìwọ ni ó ni ojúṣe (ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àdéhùn wọ̀nyí) fún ọjà yòówù tí o bá bèèrè fún tàbí fún iye owó yòówù tó lè wà fún sísan kó tó tó àkókò irú ìfòpinsí bẹ́ẹ̀. Microsoft lè yí Ibi ìpamọ́ náà padà, dẹ́kun àti tajà níbẹ̀, tàbí kó dá Ibi ìpamọ́ náà dúró pátápátá nígbà yòówù, fún ìdí yòówù, láì sọ fún ọ tẹ́lẹ̀.

26. Àwọn Àtìlẹ́yìn àti Ìhámọ Nípa Iye owó Àtúnṣe. TÍTÍ DÉ IBITÍ ÒFIN AGBÈGBÈ RẸ GBANI LÁÀYÈ DÉ, MICROSOFT ÀTI ÀWỌN OLÙPÈSÈ ỌJÀ RẸ̀, OLÙPÍN ỌJÀ, ALÁÀTÚNTÀ, ÀTI ÀWỌN OLÙPÈSÈ ÀKÓÓNÚ KÒ ṢE ÀTÌLẸ́YÌN ỌJÀ, ÀFẸ̀HÌNTÌ TÀBÍ MÁJẸ̀MÚ KANKAN TÍ A FẸNUSỌ TÀBÍ TÍ A KÒ SỌ PÀTÓ, ÈYÍTÍ Ó KAN, FÚN ṢÍṢEÉTÀ, DÍDÁRA LỌ́NÀ TÓ TẸ́NILỌ́RÙN, YÍYẸ FÚN ÈRÈDÍ KAN PÀTÓ, AKITIYAN BÍI TI ÒṢÌṢẸ́, Ẹ̀TỌ́ OHUN-ÌNÍ, TÀBÍ ÀÌTAPÁ SÍ ÀDÉHÙN. ÀWỌN ỌJÀ TÀBÍ ÌPÈSÈ TÍ A TÀ TÀBÍ TÓ WÀ NÍ IBI ÌPAMỌ́ NÁÀ NÍ ÀTÌLẸ́YÌN, BÍ ÈYÍ BÁ WÀ RÁRÁ, LÁBẸ́ ÀWỌN ÌFOHÙNṢỌ̀KAN ÌWÉ-ÀṢẸ YÒÓWÙ TÀBÍ ÀWỌN ÀTÌLẸ́YÌN OLÙGBÉJÁDÈ TÓ BÁ WỌ́N WÁ NÌKAN. YÀTỌ̀ SÍ BÍ A ṢE PÈSÈ LÁBẸ́ ÌFOHÙNṢỌ̀KAN ÌWÉ-ÀṢẸ YÒÓWÙ TÓ BÁA WÁ TÀBÍ ÀTÌLẸ́YÌN OLÙGBÉJÁDÈ, ÀTI NÍ ÌBÁMU PẸ̀LÚ Ẹ̀TỌ́ RẸ LÁBẸ́ ÒFIN:

RÍRÀ ÀTI ÌṢÀMÚLÒ RẸ JẸ́ EWU TI ARA RẸ;

ÀWA NPÈSÈ ÀWỌN ỌJÀ ÀTI ÌPÈSÈ "BÍ WỌN ṢE RÍ", "PẸ̀LÚ GBOGBO ÀBÙKÙ", ÀTI "BÍ WỌN ṢE WÀ";

O GBA EWU TÓ WÀ NÍPA DÍDÁRA ÀTI IṢẸ́-ṢÍṢE WỌN; ÀTI

O GBA GBOGBO IYE OWÓ ÌTỌ́JÚ TÀBÍ ÀTÚNṢE TÓ YẸ.

MICROSOFT KÒ ṢE ÀFẸ̀HÌNTÌ KANKAN NÍPA ÌṢEDÉÉDÉ TÀBÍ IṢẸ́-ṢÍṢE LÁKOKO ÀWỌN ÀLÀYÉ TÓ WÀ LÁTI INÚ IBI ÌPAMỌ́ TÀBÍ ÀWỌN ÌPÈSÈ NÁÀ. O GBÀ PÉ ÀWỌN Ẹ̀RỌ KỌMPUTA ÀTI TI ÌBÁRAẸNISỌ̀RỌ̀ KÒ WÀ LÁÌSÍ ÀṢÌṢE ÀTI PÉ ÀKÓKÒ ÀÌṢEDÉÉDÉ A MÁ A WÁYÉ LẸ́Ẹ̀KỌ̀Ọ̀KAN. ÀWA KÒ ṢE ÀTÌLẸ́YÌN PÉ ÀNFÀNÍ ÀTI WỌLÉ SÍ IBI ÌPAMỌ́ TÀBÍ ÌPÈSÈ NÁÀ YÓÒ JẸ́ ÈYÍ TÍ KÒ NÍ ÌDÁDÚRÓ KANKAN, TÍ YÓÒ LỌ GEERE LASIKO, PẸ̀LÚ ÀÀBÒ, LÁÌNÍ ÀṢÌṢE TÀBÍ PÉ KÌ YÓÒ SÍ ÀDÁNÙ ÀKÓÓNÚ RÁRÁ.

Bí ó bá jẹ́ pé, pẹ̀lú Àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí, o ṣì ní ìdí láti gba àsanpadà fún ìbàjẹ́ tó wáyé nípasẹ̀ tàbí TÓ NÍÍ ṢE PẸ̀LÚ Ibi ìpamọ́ náà, àwọn Ìpèsè, tàbí ọjà tàbí ìpèsè tí à nṣe, TÍTÍ DÉ IBITÍ ÒFIN TÓ YẸ GBANI LÁÀYÈ DÉ, àtúnṣe rẹ ni láti gbà lọ́wọ́ Microsoft tàbí àwọn olùpèsè RẸ̀, àwọn aláàtúntà, olùpín ọjà, àti àwọn olùpèsè àkóónú, àpapọ̀ àsanpadà tó tó (1) iye owó oṣù kan fún ìpèsè, ìṣaláàbápín, tàbí irú owó bẹ́ẹ̀ (èyí tí kò kan iye owó ríra ẹ̀yà àfojúrí, ẹ̀yà àìrídìmú, àtìlẹ́yìn, tàbí àtìlẹ́yìn tí a fàgùn), tàbí (2) US $100.00 bí kò bá sí ìpèsè, ìṣaláàbápín, tàbí irú owó bẹ́ẹ̀.

O LÈ NÍ ÀWỌN Ẹ̀TỌ́ KAN LÁBẸ́ ÀWỌN ÒFIN AGBÈGBÈ RẸ. KÒ SÍ OHUNKÓHUN NÍNÚ ÀDÉHÙN YÌÍ TÍ A GBÈRÒ PÉ KÍ Ó NÍ IPA LÓRÍ ÀWỌN Ẹ̀TỌ́ WỌ̀NYÍ, BÍ WỌ́N NÍ IPA.

Fún àwọn aṣàmúlò ìkẹyìn tí ngbé ní New Zealand, o lè ní àwọn ẹ̀tọ́ kan lábẹ́ àwọn Òfin Àtìlẹ́yìn Ọjà Aṣàmúlò Ìkẹyìn New Zealand, kò sì sí ohunkóhun nínú Àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí tí a gbèrò láti ní ipa lórí àwọn ẹ̀tọ́ náà.

27. Ìdíwọ̀n Ojúṣe. TÍTÍ DÉ IBITÍ ÒFIN TÓ YẸ GBANI LÁÀYÈ DÉ, O GBÀ PÉ ÌWỌ KÒ LÈ GBA ÀSANPADÀ FÚN ÌBÀJẸ́ TÀBÍ ÀDÁNÙ YÒÓWÙ MÌÍRÀN, ÈYÍTÍ Ó KAN ÀWỌN TÓ TI ÌDÍ OHUN KAN JÁDE, ÀKÀNṢE, TÍ KÒ LỌ TÀÀRÀ, TÓ TI IPASẸ̀ ÌṢẸ̀LẸ̀ KAN WÁYÉ, TÀBÍ ÀWỌN ÌBÀJẸ́ TÓ WÁYÉ NÍPASẸ̀ ÌFÌYÀJẸNI, TÀBÍ ÀWỌN ÈRÈ TÍ A PÀDÁNÙ. Àwọn ìhámọ́ àti ìyọkúrò TÓ WÀ NÍ ABALA 26 ÀTI 27 ní ipa, ìbáàṣepé o tilẹ̀ yẹ fún àsanpadà, àti bí a bá tilẹ̀ mọ̀ tàbí tó yẹ kí a mọ̀ nípa ṣíṣeéṣe àwọn àdánù náà. ÀWỌN ÌPÍNLẸ̀ TÀBÍ AGBÈGBÈ/àlà ilẹ̀ KAN KÒ GBA ÌYỌKÚRÒ TÀBÍ ÌHÁMỌ́ FÚN ÀSANPADÀ TÓ TI IPASẸ̀ ÌṢẸ̀LẸ̀ KAN WÁYÉ TÀBÍ TÓ TI ÌDÍ OHUN KAN JÁDE LÁÀYÈ, NÍTORÍ NÁÀ, ÌYỌKÚRÒ TÀBÍ ÌHÁMỌ́ TÓ WÀ LÓKÈ YÌÍ LÈ MÁ NÍ IPA LÓRÍ RẸ.

Títi dé ibití òfin tó yẹ gbani láàyè dé, àwọn ìhámọ́ àti ìyọkúrò wọ̀nyí ní ipa lórí Gbogbo Ẹ̀SÙN, LÁBẸ́ ÀLÀYÉ OLÓFIN YÒÓWÙ, tó níí ṣe pẹlú Ibi ìpamọ́ náà, Àwọn Ìpèsè náà, àwọn àdéhùn ìtajà wọ̀nyí, tàbí ọjà tàbí ìpèsè yòówù tí à nfifúnni, èyítí ó kan pípàdánù àkóónú, kókóró búburú TÀBÍ AṢÈJÀMBÁ yòówù tó nkan ìṣàmúlò Ibi ìpamọ́ tàbí Àwọn Ìpèsè náà TÀBÍ ỌJÀ TÀBÍ ÌPÈSÈ YÒÓWÙ TÍ A RÀ LÁTI IBI ÌPAMỌ́ NÁÀ; ÀTI àwọn ìdádúró tàbí ìkùnà ní bíbẹ̀rẹ̀ tàbí ní píparí gbígbé àlàyé láti ibìkan sí ibòmíràn lórí ẹ̀rọ tàbí ní ṣíṣe idunadura.

28. Ṣíṣe Ìtumọ̀ Àwọn Àdéhùn Wọ̀nyí. Gbogbo abala Àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí ní ipa títí dé ibití òfin tó tọ́ gbani láàyè dé; ìwọ lè ní àwọn ẹ̀tọ́ tó ju èyí lọ ní agbègbè ibití ìwọ ngbé lábẹ́ òfin (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, ibití olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà). Bí ó bá wáyé pé a kò lè lo abala kan lára àwọn Àdehùn Ìtajà wọ̀nyí bí a ti kọ ọ́, a lè fi àwọn àdéhùn tó jọ́ èyí rọ́pò àwọn irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ títí dé ibití wọ́n ti ṣeé lò dé lábẹ́ òfin tó yẹ, ṣùgbọ́n àwọn tó kù lára àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí kì yóò yípadà. Àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí wà fún ànfàní ìwọ àti àwa níkan; wọn kò sí fún ànfàní ẹlòmíràn, àfi fún àwọn tí yóò jogún Microsoft àti àwọn tí Microsoft bá yàn. Àwọn àdéhùn mìíràn lè ní ipa bí o bá ra ọjà tàbí ìpèsè láti àwọn ààyè ayélujára Microsoft mìíràn.

29. Fífifúnni. Títí dé ibití òfin tó yẹ gba ni láàyè dé, a lè pín àwọn ẹ̀tọ́ àti ojúṣe wa lábẹ́ àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí fún ni, filénilọ́wọ́ tàbí kí á fifún ni, lódidi tàbí láwẹ́láwẹ́, nígbà yòówù láì sọ fún ọ. O kò gbọdọ̀ pín ẹ̀tọ́ yòówù lábẹ́ àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí fúnni tàbí kí o fifún ẹlòmíràn.

30. Àwọn Àkíyèsi àti Ìbánisọ̀rọ̀. Fún àwọn ìbéèrè nípa àtìlẹyìn oníbàárà, jọ̀wọ́ wo Ojú-ìwé Ìtajà àti Àtìlẹ́yìn ní Ibi ìpamọ́ náà. Fún àríyànjiyàn, tẹ̀lé ìlànà àkíyèsi ní abala yìí.

31. Ẹnití nbá ni dá Májẹmù, Àṣàyàn Òfin àti Ibití a ó ti Parí Àríyàjiyàn.

a. Àríwá tàbí Gúsù Amẹrika lóde United States tàbí Canada. Bí o bá ngbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Àríwá tàbí Gúsù America lóde United States tàbí Canada, ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Corporation, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Àwọn òfin ìpínlẹ̀ Washington ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí, ẹ̀tọ́ gbígbà fún títàpá sí wọn, láì ka àṣàyàn òfin tó rọ̀ mọ́ èyí kún. Àwọn òfinorílẹ̀-èdè ibiti à ndarí Ibi ìpamọ́ àti àwọn Ìpèsè náà sí ni o ndarí gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ (eyiti o kan ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, fífiga-gbága ti kò tọ́, ati òfin ti ndarí ìwà àìtọ́).

b. Middle East tàbí Africa. Bí o bá ngbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Middle East tàbí Africa, ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Ireland Operations Limited, The Atrium Building, Block B, Carmanhall Road, Sandyford Industrial Estate, Dublin 18, Ireland. Àwọn òfin Ireland ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí àti àwọn ẹ̀tọ́ gbígbà fún títàpá sí wọn, láì ka awọn òfin miiran tó rọ̀ mọ́ èyí, ti wọ́n sì lè yàtọ̀ síi kún. Àwọn òfin orílẹ̀-èdè ibiti à ndarí Ibi ìpamọ́ àti àwọn Ìpèsè náà sí ni o ndarí gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ (eyiti o kan ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, fífiga-gbága ti kò tọ́, ati òfin ti ndarí ìwà àìtọ́). Ìwọ àti àwa faramọ́, láìsí àyípadà ọkàn, pé sàkání ẹjọ́ àti àwọn ilé-ẹjọ́ Ireland ní a ó ti dá ẹjọ́ àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí tabí Ibi ìpamọ́ náà.

c. Asia tàbí Gúsù Pacific, àfi fún àwọn orílẹ̀-èdè tí a dárúkọ nísàlẹ̀ yìí. Bí o bá ngbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Asia (yàtọ̀ sí China, Japan, Republic of Korea, tàbí Taiwan), ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Regional Sales Corporation, ilé-iṣẹ́ tí a dásílẹ̀ lábẹ́ àwọn òfin Ìpínlẹ̀ Nevada, U.S.A., pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ rẹ̀ ní Singapore àti Hong Kong, àti olú ilé-iṣẹ́ rẹ̀ ní 438B Alexandra Road, #04-09/12, Block B, Alexandra Technopark, Singapore, 119968. Àwọn òfin ìpínlẹ̀ Washington ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí, àti àwọn ẹ̀tọ́ gbígbà fún títàpá sí wọn, láì ka awọn òfin miiran tó rọ̀ mọ́ èyí, ti wọ́n si le yàtọ̀ síi kún. Àwọn òfin orílẹ̀-èdè ibiti à ndarí Ibi ìpamọ́ náà sí ni o ndarí gbogbo gbígba ẹ̀tọ́ mìíràn yòókù (eyiti o kan ààbò aṣàmúlò ìkẹyìn, fífiga-gbága ti kò tọ́, ati òfin ti ndarí ìwà àìtọ́). Àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí tàbí Ibi ìpamọ́ náà, títí kan ìbéèrè yòówù tó níí ṣe pẹ̀lú wíwà wọn, wíwúlò, tàbí píparí iṣẹ́, ni a ó mẹ́nubà, tí a ó sì yanjú nípasẹ̀ ìlàjà ní Singapore ní ìbámu pẹ̀lú Àwọn Òfin Ìlàjà ti Singapore International Arbitration Center (SIAC), awọn òfin èyí tí a kà kún pé a kọ sínú gbólóhùn kúkúrú yìí. Àjọ àwọn adájọ́ náà yóò ní onílàjà kan nínú, èyí tí Ààrẹ SIAC yóò yàn. Èdè tí a ó lò fún ìlàjà náà yóò jẹ́ Gẹ̀ẹ́sì. Ìpinnu onílàjà náà yóò jẹ́ ìdájọ́ ìkẹyìn, èyí tí a gbọ́dọ̀ tẹ̀lé, a ki yóò si lè jiyàn rẹ̀, a sì lè lòó gẹ́gẹ́ bíi ìlànà fún ìdájọ́ ní orilẹ̀-èdè yòówù.

d. Japan. Bí o bá ngbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Japan, ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Japan Co., Ltd (MSKK), Shinagawa Grand Central Tower, 2-16-3 Konan Minato-ku, Tokyo 108-0075. Àwọn òfin Japan ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí àti àwọn ẹjọ́ yòówù tó lè wáyé láti inú wọn tàbí Ibi ìpamọ́ náà.

e. Republic of Korea. Bí o bá ngbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Republic of Korea, ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Korea, Inc., 11th Floor, Tower A, K-Twin Tower, Jongro 1 gil 50, Jongro-gu, Seoul, Republic of Korea, 110-150. Àwọn òfin Republic of Korea ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí àti àwọn ẹjọ́ yòówù tó lè wáyé láti inú wọn tàbí Ibi ìpamọ́ náà.

f. Taiwan. Bí o bá ngbé ní (tàbí, bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́, tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ wà ní) Taiwan, ìwọ nṣe àdéhùn pẹ̀lú Microsoft Taiwan Corporation, 18F, No. 68, Sec. 5, Zhongxiao E. Rd., Xinyi District, Taipei 11065, Taiwan. Àwọn òfin Taiwan ni ó ndarí ìtumọ̀ àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí àti àwọn ẹjọ́ yòówù tó lè wáyé láti inú wọn tàbí Ibi ìpamọ́ náà. Fún àlàyé síwájú síi nípa Microsoft Taiwan Corporation, jọ̀wọ́ wo àyè ayélujára tí a pèsè láti ọwọ́ Ministry of Economic Affairs R.O.C. (https://gcis.nat.gov.tw/main/index.jsp). Ìwọ àti àwa yan, láìsí àyípadà ọkàn, Ilé-ẹjọ́ Taiwan Taipei District gẹ́gẹ́ bí ilé-ẹjọ́ àkọ́kọ́ tó ní ẹ̀tọ́ láti dá ẹjọ́ lórí àríyànjiyàn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ tàbí tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn Àdéhùn wọ̀nyí tabí Ibi ìpamọ́ náà, títí dé ibití òfin Taiwan gba ni láàyè dé.

32. Àwọn Àkíyèsi.

a. Àwọn àkíyèsi àti ìlànà fún mímú ẹ̀sùn wá fún títàpá sí ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ ẹni. Microsoft nbọ̀wọ̀ fún àwọn ẹ̀tọ́ ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ àwọn ẹlòmíràn. Bí o bá fẹ́ fi àkíyèsi nípa ìtàpá sí ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ rẹ ránṣẹ́, èyí tí ó kan ẹ̀sùn fún ìtàpá sí ẹ̀tọ́ ọjà-títa, jọ̀wọ́ lo ìlànà wa fún fífi Àwọn Àkíyèsi Ìtàpásí ránṣẹ́ (https://www.microsoft.com/info/cpyrtInfrg.aspx). GBOGBO ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÍ KÒ BÁ ÌLÀNÀ YÌÍ MU KÌ YÓÒ GBA ÈSÌ.

Microsoft a má a lo àwọn ìlànà tí a gbékalẹ̀ ni Àkórí 17, Kóòdù United States, Abala 512 láti fèsì sí àwọn àkíyèsi nípa ìtàpá sí ẹ̀tọ́ ọjà-títa. Ní àwọn ìgbà tó yẹ, Microsoft lè mú àkọọ́lẹ̀ àwọn aṣàmúlò àwọn iṣẹ́ Microsoft tó jẹ́ olùtàpá sí ẹ̀tọ́ nígbà gbogbo má ṣiṣẹ́ tàbí kí ó múu dópin.

b. Àwọn Àkíyèsi nípa Ẹ̀tọ́ Ọjà-títà àti Ààmì Ọjà-títà.

Gbogbo àwọn àkóónú Ibi ìpamọ́ àti àwọn Ìpèsè náà jẹ́ Ẹ̀tọ́ ọjà-títà © 2016 Microsoft Corporation àti/tàbí àwọn olùpèsè rẹ àti àwọn ẹlòmíràn tí npèsè ọjà fún-un, One Microsoft Way, Redmond, WA 98052, U.S.A. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà ni ìpamọ́. Àwa tàbí àwọn olùpèsè wa àti àwọn ẹlòmíràn tí npèsè ọjà fún wa ni ó ni ẹ̀tọ́ ohun-ìní, ẹ̀tọ́ ọjà-títà, àti àwọn ẹ̀tọ́ ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ mìíràn ti Ibi ìpamọ́, àwọn Ìpèsè àti àkóónú náà. Microsoft àti àwọn orúkọ, ààmì ìdánimọ̀ ọjà, àti àwọn àwòrán inú ẹ̀rọ gbogbo ọjà àti ìpèsè Microsoft lè jẹ yálà ààmì ọjà-títà tàbí ààmì ọjà-títà Microsoft tí a forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ ní United States, Canada àti/tàbí ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

A lè rí àkójọ àwọn ààmì ọjà-títà Microsoft ní: https://www.microsoft.com/trademarks. Àwọn orúkọ àwọn ilé-iṣẹ́ àti ọjà gidi lè jẹ́ ààmì ọjà-títà àwọn oníhun wọn. Àwọn ẹ̀tọ́ yòówù tí a kò fífún ni nínú àwọn Àdéhùn Ìtajà wọ̀nyí wà ní ìpamọ́.

33. ìkìlọ̀ Ààbò. Láti yàgò fún ìpalára, ìnira tàbí dídá ojú ẹni lágaara, ọ gbọ́dọ̀ ní ìsinmi láti ìgbà dé ìgbà kúrò lẹ́nu lílò àwọn eré tàbí ohun èlò mìíràn, pàápàá bí o bá nní ìrora tàbí bí ó bá nrẹ̀ ọ́, àwọn èyítí ó nwáyé nípasẹ̀ ìmúlò. Bí o bá ní ìrírí ìnira yòówù, ṣíwọ́ nínú eré. Ìnira lè jẹ́, kí èébì má a gbé ni, àìlera ìrìn-àjò, òòyì, àìmọ ibi tí ènìyàn wà, orí-fifọ́, àárẹ̀, dídá ojú ẹni lágaara, tàbí ẹyin ojú aláìlómijé. Lílò àwọn ohun èlò lè fa ìdíwọ́ ní fífọkànsí nkan, ó sì tún lè dínà mọ́ ọ ní àyíká rẹ. Yàgò fún àwọn ohun tó lè gbé ni ṣubú, àbágùnkè, àjà ilé tí kò ga sókè púpọ̀, àwọn ohun ẹlẹgẹ́ tàbí tó níyelórí, tó lè bàjẹ́. Àwọn ènìyàn méèló kan lè ní ìrírí gìrì nígbàtí wọn bá wà lábẹ́ agbára àwọn àwòrán àfojúrí bíi àwọn iná tó nṣá tàbí tó nṣẹ́jú tó lè má a hàn nínú àwọn ohun èlò náà. Àwọn ènìyàn tí kò ní ìtàn nípa gìrì pàápàá lè ní àìsàn tí a kò tíì yẹ̀wò, èyí tó lè fa àwọn gìrì wọ̀nyí. Àwọn ààmì àìsàn lè jẹ́ òòyì, àìríran dáradára, gbigbọ̀n ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀, àìmọ ibití ènìyàn wà, àìmọ ohun tí ènìyàn nṣe, dídákú, tàbi àìpérí. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ dẹ́kun lílò, kí o sì kàn sí dọ́kítà bí o bá nní èyíkéèyí nínú àwọn àmì àìsàn wọ̀nyí, tàbí kí o kàn sí dọ́kítà kí o tó lo ohun èlò náà bí o bá ti ní irú àmì àìsàn tó níí ṣe pẹ̀lú gìrì rí. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣàkóso bí àwọn ọmọ wọn ti nlo àwọn ohun èlò, kí wọ́n sì ṣàkíyèsi àwọn àmì àìsàn wọ̀nyí.